![]() |
Kemi Nelson |
![]() |
Alhaja Abiodun ti won se lese |
Ṣe
lọrọ di bo-o-lọ-o-ya-go lọjọ Aje, Monde nigba ti wahala be sile ni ọfiisi
ẹgbẹ oselu APC
to wa ni Acme, niluu Eko nibi ti awon toogi oloselu ti kolu Jumoke Okoya Thomas, ti won
si se amugbalegbe e lese repete.
Ohun ta a gbo ni pe, wahala
kan to wa laarin gbajumo oloselu nni, Kemi Nelson ati Jumoke Okoya Thomas lo fa
ruke-rudo ohun. Eni ti isele ohun soju e, to je omo egbe APC to ni ki a foruko bo
oun lasiiri so pe bi awon tọọgi ọmọlẹyin Kẹmi Nelson ṣe wole egbe ohun ni won lo
ba Jumoke Thomas, ti won si kilo fun un wi pe ko sora e gidigidi.
Jumọke
Ọkọya Thomas yii ni wọn sọ pe oun lo jẹ aṣaaju awọn obinrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC
nipinlẹ Eko nigba ti Kẹmi Nelson to ti wa nipo naa tẹlẹ ti wa nipo asaaju awon obinrin
oloṣelu ẹgbẹ ọhun nilẹ Yoruba bayii. Won ni ipo ti Jumoke wa yii
ko tẹ Kẹmi lọrun, iyen gan-an ni won lo n fa wahala nla laarin won.
Gẹgẹ
bi iwadii oniroyin wa, ibi ipade pẹlu alaga ẹgbẹ oṣelu naa, Tunde Balogun ni
wọn wa lọjọ naa ti awọn tọọgi yii fi yawọ ibẹ. Okan
ninu wọn ti wọn pe oruko ẹ ni Ayọ Ali Balogun lo lo
ba Okoya Thomas, to si sọ fun un pe ko sọ ara ẹ daadaa, ti ko ba fe ri wahala repete.
Ere
lawọn to wa nibi ipade naa kọkọ pe e ti wọn si ya ẹnu wọn pe ki lo le fa iru iwa bee. Won
ni pẹlu gbogbo bi tọọgi yii se n
dunkoko mo obinrin
oloselu naa, nise lo n wo o ti ko sọ nnkankan.
Ṣugbon
nigba ti eṣu Ayo Alli Balogun ri i pe iyẹn ko ṣee ṣe ni won lo
bọ sita to si n wa ibi ti amugbalẹgbẹ obinrin, iyen Alhaja Abiodun. Won nibẹ gan-an lo ti kọ lu Abiodun, to si je iyen niya daadaa,
eyi to mu ki ẹjẹ maa jade lara ẹ ti wọn si sare gbe e lọ sile
iwosan.
Okan lara awon omo egbe
naa so pe, o se die ti wahala naa ti bẹrẹ, paapaa
nigba ti Jumọke Thomas di aṣaaju ẹgbẹ obinrin naa nipinlẹ Eko ṣugbọn ti Kẹmi
Nelson to ti wa nibẹ tẹlẹ kọ lati fa iṣẹ le e lọwọ, to si tun ko lati
kuro lofiisi fun un. Wọn
ni gbogbo ọna lawọn to sunmọ awọn mejeeji ti sa lati ri i pe wọn yanju aawọ naa
ṣugbọn ti ko yanju rara.
0 Comments