GBAJUMO

ASIRI OHUN TO N MU AWON EEYAN KUNA LATI ROWO YA LOWO IJOBA - ALASE YEFADOT

Oloye Yetunde Babajide
Aare, ileese YEFADOT
Lati le mu igbe aye irorun ba araalu, Aare ileese YEFADOT Group of companies Oloye Yetunde Babajide ti so pe, ileese oun ti setan lati ran awon eeyan lowo ki igbe aye irorun le kari laarin lawujo.
Nibi ipate ita gbangba ati eto ekose-owo to bere lojo ketadinlogbon titi di ogbonjo osu keje yii ti ileese YEFADOT ati ileese ijoba to n ri si oro aje ati ileese (Lagos state ministry of commerce and industry) sagbateru e lo ti so o laipe yii.
Ninu oro e lo ti so pe, “Ko soro fun eeyan lati tete goke, ohun to se pataki ni ki eeyan kose owo kan, ko si fi suuru se e. Ise agbe si ti rorun pupo fun wa lati se bayii, bee ni ijoba apapo ti la orisirisi ona sile fun awon eeyan to je anfaani nla. Eto eyawo wa lorisirisi, bi won se le rin in lopo eeyan ko mo, iyen gan-an ni ki i je ki won ri owo ya rara. Opolopo a ni awon fe fowo sise ag
be, won a si fe iranwo owo lowo ijoba tabi banki, sugbon ti won ki i mo idi ti won ki i fi ri eyawo yii gba.
“Ohun to sele ni pe, won n pe kinni kan ni business plan, iyen bi eeyan se fe se okoowo yen gan-an. Iwo to ba fe gbowo lowo ijoba fi sise agbe, o se pataki ki o ni eto bi o se fe nawo, owo yen paapaa, iwo ati banki le o jo na, nitori won yoo  maa sakoso bi o se n na an, eyi ti ko fi ni i bo si inakuna. O gbodo le salaye iye ti wa fi ra ile, iye ti wa fi ra kemika, oye ti o fe na lori ohun ti o fe gbin, iye ti awon osise maa gba, iye ti iwo naa a maa gba losoosu, ti awon nnkan wonyi ba ti wa ninu eto, o di dandan ki ijoba ya iru eni bee lowo. Ti awon eeyan ba gbe iru isoro yii de odo wa, Olorun n fun wa loore ofe lati ba won yanju e, ti won si n resi ayo nigbeyin.”
Awon olukopa
Iyalode Ojodu fi kun oro e pe, orisi nnkan meji lawon eeyan yoo lanfaani lati maa ko titi ti eto ohun yoo fi kase nile lojo Isegun, Tusde to n bo.  Ninu oro e naa lo ti so pe, “Lara ohun ti a la sile ninu eto yii ni bi a o se ko awon eeyan lorisirisi ise owo ti yoo maa dowo fun won. Bi won ba se n n lo o funra won ninu ile, bee ni won le maa ta a, ti won yoo si maa ri owo fi se nnkan rere.
“Yato si eyi, anfaani tun wa fawon omo wa lati ko orisirisi nnkan to le se won lanfaani, paapaa lasiko olide ti won wa yii, nitori e la se ni ki awom obi ko awon omo won wa sibi eto yii lati kekoo. Nibi ti aye baje de loni-in, omo odun mejidinlogun kan lowo te, to n ka boroboro wi pe o to eeyan merin ti oun ti pa, ti irufe omobinrin yii ba pe eni ogoji odun, ta lo mo iye eni to maa pa? Nitori idi eyi, la se ni lati sunmo awon omo wa. Opo obi ni won ti jinna si omo won, irufe ohun bayii ko le mu awujo wa te siwaju”
Lara awon ti won tun fun awon eeyan ni idanilekoo lojo naa ni Ogbeni Kuti George, ninu alaye e lo ti ro awon araalu lati san sokoto won ki o le daadaa, ki won si fi ise agbe gba ara won kale lowo ise ati ebi. O ni, “Loooto Agbe l’Oba, ojo ola awon agbe si dara lorile-ede yii, ti ijoba ba so pe oun ko setan lati ran yin lowo, eyin naa le ko ara jo, ki e da egbe alajeseku sile, latara bee, e le maa ya ara yin lowo. Yato si eyi, ohun kan ti mo mo ni pe, ti eeyan kan ba da rin, irufe eni bee le rin kanmo-kanmo, sugbon o ni ibi ti irufe eni bee le rin de, sugbon ti opo eeyan ba rin papo, won maa lo jinna , bee ni aseyori  gidi a si wa pelu. Ohun mi-in ti a tun le se gege bi agbe, eni kan le ra katakatya, ki awon mi-in naa tun ra ohun elo mi-in, ti e o jo maa lo o papo, irufe eyi yoo mu ilosiwaju nla wa, ti yoo si mu idagbasoke ba orile-ede.”
Lara awon ogo-weere ti won wa gba idanilekoo


Post a Comment

0 Comments