GBAJUMO

ASIRI NLA TO WA LAARIN SULE ALAO MALAIKA ATI OLUBADAN TONI, ALAYELUWA OBA SALIU ADETUNJI

Alayeluwa Sule Alao Malaika ati Olubadan gbogbo ile Ibadan pata, Oba Saliu Adetunji

Nigboro ilu Eko ni nnkan bi odun merindinlogoji, omo kekere kan wa, ko ti i ju omo odun mewaa si mokanla lo nigba yen, o gbon ninu daadaa, bee ipo asaaju lo wa laarin awon to mo orin ko, iyen orin ajiwere ti won fi maa n ji awon Musulumi lasiko aawe. Omo ti a n so yii, Sule o n je o, iyen Sulaimon Alao Adekunle, omo kekere patapata ni; nigba yen, sugbon eeyan nla kan ni, ti opolo e pe pupo ti a ba n so nipa ka hun orin, ka si gbe e kale lona to yaayi daadaa.
Omo Ago Owu ni niluu Abeokuta, nipinle Ogun, bee lo tun tan daadaa mo won niluu Ibadan, nitori Ibadan ponbele ni mama to bi Sule n se.
Lasiko ti a n wi yii, o fe ma si ode were tabi idije ajiwere kan ti won yoo gbe kale nigboro Eko ati agbebe e ti Sule Alao ko ni i fa ako yo nibe, ti yoo tun gba ade.
Bo se bere ree o, ki oloju si too se e, Sule ti daraba nla laarin awon olorin, nigba ti ori yoo si ba a se, bo se pade baba agbalagba kan, ti iyen maa n gbe rekoodu awon olorin jade, iyen Alhaji Saliu Adetunji, eni to ni ileese Babalaje Records.
Alao ati iyale e ree,
Bukola, Omooba Olubadan
Sugbon saaju ki o too pade baba yii, omodebinrin kan wa niluu Eko, Basirat Olubukola Saliu Adetunji loruko e, omo Ibadan ni, iyen ilu ti Mama Sule Malaika ti wa. Obinrin yii loun ati Alao omo Adekunle jo n tele ara won kiri, ki oloju si too se e, ife ijinle ti duro saarin won, bi Sule se fe e niyen, ti o si se bee di ana Alhaji Saliu Adetunji.
Se ori ti yoo gbe ni, lo maa n gbe alawo rere ko ni,  obirnin ti Sule Alao fe nisu loka yii, iyen Olubukola, ase omo Alhaji Saliu Adetunji ni, baba yen gan an lo ni ileese Omo Aje records. Odun keji to fe omo agba oje nidii ise awon to n se igbelaruge fawon to n korin ni Malaika darapo mo ileese naa, bi Olorun se gbadura Alayeluwa niyen o, ti okiki n kan lojoojumo, ti irawo si n tan kaakiri agbaye.
Ninu oro Malaika gan-an funra e lo ti so pe, “Baba mi gan-an ni Olubadan n se, won ko fowo ana mu mi, bii omo ni mo se je si won. Ni temi o, ohun meji ni Olubadan je si mi, iwuri nla lo je fun mi wi pe, okan lara awon olorin ti ileese won n gbe rekoodu e jade ni mo je, yato si pe mo je ana won. Bakan naa lo tun je pe awon ni won gbe gbogbo rekoodu ti mo ti se jade lati bi odun metalelogun seyin. Ana daadaa ni Olubadan je fun mi, bee lomo won ti mo fe naa je iyawo alalubarika to mu ohun gbogbo rorun fun mi lodede mi.”
Oun ati iyawo kekere
Bo tile je pe omo ipinle Ogun ni, sibe igboro Eko ni won bi i si lojo kerinla osu keji odun 1973. Lara awon ibi ti Alayeluwa Sule Alao Malaika gbe daadaa pelu awon obi e ni kekere ni Mushin, Osodi, Agege ati igboro Eko gangan, iyen Lagos Island.
Awon ileewe to lo ni Oyewole Primary School ati Yewa High School, ilu Agege, l’Ekoo lawon ileewe mejeeji yii wa.
Gege bi Musulumi ododo, to maa n kirun daadaa, odun 1999 loun naa darapo mo awon Musulumi yooku lagbaye lati josin niluu Mecca, eyi to so Sule Alao Malaika di Alhaji laarin awon olorin fuji egbe e.
Bee gege lo tun lo si Mecca lodun 2005, ti o si tun ti se bee laimoye igba lati josin fun Olorun.
Alimat ree, akobi e lojo to
kawe gboye ni Yunifasiti Eko
Ti won ba n so nipa olorin fuji to ni molebi to se mu yangan, ojulowo ni Madiba n se, o niyawo, bee lo sabiyamo daadaa, koda iwe ti Malaika ko lanfaani lati ka doju ami, gbogbo awon omo ti Olorun fun un loni-in ni won n kawe, ti won si n moke daadaa lenu eko won. Laipe yii ni akobi e, Alimat Sadia kawe gboye nla ni Yunifasiti Eko, iyen UNILAG.
Yato si Olubukola omo Olubadan to fe, obinrin arewa mi-in naa tun wa nile Alayeluwa loni-in, eyi to so okunrin yii doniyawo meji gege bi esin Islam se la a kale fun gbogbo awon to ba n tele Anobi Muahmmed. Bee baale daadaa ni laarin awon iyawo e mejeeji.
Te o ba gbagbe, ajiwere ni won mo Malaika si nigba to bere si korin, ki oloju si too se e, oun naa ti wa lara awon to n korin fuji nigboro Eko, to si ti ni awon ololufee repete ti won ki i forin e sere rara. Nigba to di odun 1985 ni Sulaimon Adekunle da egbe orin e sile, eyi to pe ni Tekoye Fuji Organization, bo tile je pe o ti ni awon eeyan ti won jo n korin were kiri tele.

Bi ojo ti n n gori ojo ni omo Adekunle n goke si i, ti orin e si se kerekere dohun ti won n gbo kaakiri agbaye.
Loni-in, oruko egbe akorin e ni MALAIKA FUJI ORGANIZATION, odun 1997 lo yi oruko pada kuro ni Tekoye to koko n je lodun 1985 nigba to da egbe akorin e sile. Nigba to tun di odun 2005 ni egbe ohun tun gba oruko tuntun, eyi to n je titi di asiko yii The Pride of Fuji band, eeyan marun-din-logoji  ni won jo n sise papo ninu egbe akorin naa, bee kaakiri agbaye ni won jo maa n lo.
· Lara awon omoleyin e ni Alhaji Abiodun Alashe Soaga eni tawon eeyan tun mo si T.A Showkey, oun lo maa n gberin leyin e bee ni Alhaji Shola Arowoshaiye naa wa nibe ti oun wa nipo Manija gbogbo-gboo.
O ti le ni ogbon orile-ede kaakiri agbaye ti Sulaiman Adekunle ti lo korin pelu awon elegbe e, ti irawo e pelu okiki nla to ni nidii ise fuji si n tan gidigidi kaakiri agbaye.
Lara awon rekoodu ti Malaika se niwonyi:

·         MrWonder (1994) * Masterpiece (1995) Legend (1996), Malaika (1997), American Dream (1998, Correction (1999), Recompense (2000), CNN (2001),Unstoppable (2002), Interlink (2003), Peace Maker (2004); Alayeluwa (2005), European Knockout (2006), Dedication (2007), Appreciation (2007),  Elevator and Motivator (2009), Proper Music (2011), Special day (2012),Superstar (2014),Original (2016), Golden Jubilee (2017) ati bee bee lo
EYI TO SE PELU AWON OLORIN MI-IN
·         Unity
·         Gbeborun
·         My Mother
·         Double Malaika
·         Fuji Gyration (Wasiu Alabi Pasuma)
·         5 & 6
·         Shine Shine Bobo
·         Africa like Europe (Wasiu Alabi Pasuma)
·         Appreciation (Wasiu Alabi Pasuma)
·         Unification (Wale Ayinde Tekoma & Wasiu Alabi Pasuma)
·         3 pillar
·         See Wonder
·         Yara Rebete
·         Fuji Lawa
·         Online
·         Takbir

 AWON ONISEJU PERETE TO SE NIWONYI
Boshenjo (Oun ati Olamide ni won jo se e)
·         Stop the violence (Oun ati Oritshefemi, Dude Tetsola pelu Cashson ni won jo se e)
·         Nana Dance (Oun ati Dammy Krane ni jo se e)
·         IRE
·         Iya Mi (Rukayat Gawat, Kifayat Singerr, Sofiat Iya n kaola, Mujidat Damilola, Misturah Aderounmu)
·         Ogbon ati Ete (Southy Arewa and Ajike Arewa)
·         Malaika at 44

Post a Comment

0 Comments