GBAJUMO

WAHALA WASIU AYINDE, BARITIDE ATI SAIDI OSUPA *BARRYSHOWKEY TI SO PE, ISE ALAAFIA NI BARRISTER RAN OUN SI GBOGBO ONIFUJI


Adewale Akanji Balogun, okan lara awon omo Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister toun naa n kroin, to fi ilu Amerika sebugbe ti ro gbogbo awon to tun fe bere rukerudo lagboole orin lati so gbeje mowo.
Ninu oro Akanji Barry Showkey yii lo ti so pe, oun la ala kan, ati pe Oloogbe Skiru Ayinde Barrister gan an lo yo soun loju ala, bee ni baba naa fi edun okan e han lori oro ti Alhaji Wasiu Ayinde ba awon ileese iroyin BBC Yoruba so nipa Alhaja Modinatu Asabi Barritide, ati bi Saidi Osupa naa se tun gba ileese ohun lo, nibi to ti fun Wasiu lesi wi pe, okunrin naa ko ye ninu eni to le dari awon olorin fuji.
Barry Showkey so pe awuyewuye ti won tun fe bere lagboole orin yii ki i se ohun to dun mo omo Agbajelola ninu rara, bee ni inu okunrin to da orin fuji sile yii ko dun si i, paapaa bi won ti se n peri e atawon idile e si ohun ti won tun fe maa fa mo ara won lowo bayii.
O te siwaju pe, “Mo je eni kan ti ki i da si ohun ti ko ba kan mi, ohun to ba kan mi lemi maa n ran, ti maa si gbaruku ti i,  ko le ba yanju, sugbon Yoruba lo so pe; ohun to ba ba oju; o ti di dandan ko ba imu, bee abuku kan to ba tale enikeni ninu idile Barrister, irufe abuku bee, gbogbo wa pata lo jo kan. Ati pe, mi o le fowo leran maa woran, paapaa ti oro ohun ba ni se peelu baba mi, Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister. Itara ni mo  fe fi soro tele, sugbon Olorun fun mi ni oore ofe lati lala ri baba mi loju oorun, nibi ti won ti ba mi so opolopo oro, paapaa lori bi awuyewuye to fe bere yii yoo se dohun igbagbe.

“Ninu oro won ni won ti ni ki n so fun gbogbo awon eeyan to n korin fuji wi pe , ki won ma se da wahala kankan sile, dipo bee, bi irepo se maa wa ni ki kaluku mojuto, ki orin fuji le maa te siwaju daadaa.
“Won ni ariwo ti won fe bere lori oro omo awon, Alhaja Modinatu Baritide, awon ko nifee si i, ki kaluku menu kuro lori oro ohun, nitori alaafia aarin awon onifuji lawon n fe.
“Bakan naa ni won so pe ki n kilo fun enikeni to ba n lowo si ki wahala maa wa lagboole orin wi pe iru eni bee yoo ko ibinu Olorun nidii ise to n se yii ni. Oro ti Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister so niyen o, bee lemi naa fe ro kaluku ki a koju mo ise wa, ki a fi wahala ati ote sile. Bi orin fuji yoo se te siwaju ju bayii lo, lo ye ki a mu ni okunkundun lasiko yii, ki i se ki a tun dana wahala mi-in sile”
Barryshowkey so pe, pupo ninu awon eeyan ni won feran orin fuji daadaa latara ipa ribiribi ti Alhaji Sikiru Ayinde Barrister ati enikeji e, Alhaaji Kollington Ayinla ko. O ni, iwa omoluabi ti awon eeyan mejeeji yii lo pelu orin naa lo so o di itewogba latiberepepe, sugbon ti awon ti won n ko lasiko yii n fi iwa jagidijagan fe so orin naa di ota awon eeyan gidi laarin ilu.
O fi kun un oro e bayii wi pe, “Eyin naa e wo awujo wa loni-in, omo kekere wo leyin ri to gbe igba orin fuji,? Bee ohun itiju nla lo ye ki o je fun awa ti a n ko, ki i se ija lo ye ki a tun maa ba ara wa ja kiri.

“Baba mi ati ore won, Alhaji Kollignton Ayinla se e daadaa lo se wu opolopo ti won ti di igi araba nla nibe loni-in yii. Kani awon yen ko ba gbe e daadaa ni, ki lawon to n ko o loni-in iba deba. Eleyii gan-an lo ye ko je ohun irori fun wa, dipo ija ti won tun fe fi oruko idile wa bere bayii. Awa ko fe e, bee la tako o, irepo ati alaafia ni omo Agbajelola n fe forin fuji, ki gbogbo arijagba pata lo sinmi. Ise ti Oloogbe ran mi ni mo n je o, emi naa ki i se eran riro o, baba wa lo so pe oun ko fe ariwo, bee awa loro kan, nitori oniluu ko ni i fe je ko tu laye. ko si bi won se fe soro orin fuji ti won le yo Sikiru Ayinde Barrister sile, bi won tie n dogbon e; eledaa orin fuji gan-an ko je ki aye tiwon naa dara, gbogbo wa la n ri atubotan to n sele si won bayii.
“Sugbon ju gbgbo e lo, Barrister ti so pe alaafia loun n fe, bee si lo se gbodo wa, ti a ba wa reni ti ko fe bee, afaimo ki oku orun ma bi i.
Te o ba gbagbe ni nnkan bi osu meloo kan ni Alhaja Modinatu Asabi Baritide, okan lara awon omo Alhaji Sikiru Ayinde Barrister ba awon oniroyin kan soro, nibi to ti so itan bi Alhaji Wasiu Ayindc se de odo baba e, oun naa lo fidi e mile wi pe, ki i se omo eyin elere to maa n ba won ko aga ati ero amohun-du-gbemu, iyen loud speaker nikan ni Wasiu Ayinde n se leyin Barrister, bikose pe ise agbafo gan-an lo ba de odo oloogbe ohun.

Oro yii ni Wasiiu Ayinde gbo, bi oun naa se gba ileese iroyin BBC Yoruba lo niyen to lo fun Baritide lesi. Nibe naa lo ti so pe ki i se Barrister lo bi Baritide, ati pe oro to so nipa oun, o kere pupo lati pe iru awon ede bee si oun.
Oro yii naa ni  Saidi Osupa gbo, bi oun naa se gba ileese BBC Yoruba lo niyen, to si so o ninu iforowero e wi pe Wasiu Ayinde ki i se asaaju awon, ati pe okunrin naa ko ni amuye ohun ti eeyan fi n se asaaju. Bi oro ohun se ri ree, bee ni Barritide naa ti so pe ija ko tivi tan o, ija sese bere ni, ati pe ti oun ba gba aawe tan loun yoo fun Wasiu Ayinde lesi oro e.


Post a Comment

0 Comments