GBAJUMO

ATIKU BU SEKUN LOJO TI WON GBA FOOMU IPO AARE FUN UN *O NI KO SELE RI LATIGBA TOUN TI GBEGBA OSELU

Atiku nigba to n safihan foomu
ti won gba fun un

Ọjọ manigbagbe lọjọ Eti Fraide, ojo kokanlelogbon osu kejo jẹ ninu itan igbesi aye Alhaji Atiku Abubakar, eni to ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ orile-ede yii ri nigba tawon ololufee gba foomu fun un lati dije dupo aare labe asia egbe oselu PDP.
Bi kuku-keke eto idibo odun 2019 se n gba igboro kan bayii, igbese manigbagbe tawon ti won je alatilẹyin gbajumo oselu yii gbe ni bi wọn se ko ara wọn jọ, ti wọn da owo ti wọn si fi gba a fọọmu mo nifẹẹ lati dije fun ipo aarẹ fun ọkunrin naa.
Ohun to si jẹ ko ri bẹẹ ni pe latigba ti ọkunrin naa ti wọnu oṣelu, to ti n jade lati dije fun ipo, igba akọkọ ree tawọn kan yoo ko ara wọn jọ ti wọn yoo gba fọọmu fun ọmọ Adamawa naa. Nibi tọrọ naa ya a lenu de, ko mọ igba ti omi n bọ loju ẹ to si sọ pe oun ko nireti pe awọn kan le ṣe iru nnkan bẹẹ foun laelae, ati pe igbese naa fidi e mule wi pe igbagbo nla ni won ni ninu oun.
Ofiisi ẹgbẹ oselu naa to wa ni Wuse niluu Abuja lawọn alatilẹyin ẹ yii ti fi kinni ohun ya a lenu, bee ni won so fun un pe awon nigbagbo wi pe Atiku lo ni iriri nla to fi le gbe orile-ede yii de ebute rere.
Aṣaaju awọn ikọ awọn obinrin, Ọmọọba Adekẹmi- Adesanya Ẹboda to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn obinrin to n ṣatilẹyin fun Atiku, iyẹn WAYS sọ pe awọn obinrin ti n foju sọna fun Atiku lati gba awọn ọmọ orile-ede yii silẹ lọwọ ijọba ti ko nitumọ tẹgbẹ APC n se.
O loun n gbẹnu sọ fun gbogbo awọn obinrin ti ilọsiwaju orile-ede yii jẹ pataki fun un pe ki Atiku ma ṣe boju wẹyin lati dije, ati pe gbogbo nnkan ti yoo ba na awọn lawọn yoo ṣe lati ri i pe ọkunrin naa dori ipo ohun.
E wo bo ti se bu sekun...
Ọgbẹni Edwin Adai toun naa jẹ aṣaaju lara awọn alatilẹyin lo gbe fọọmu naa le Atiku lọwọ lorukọ gbogbo wọn.
 Nigba to n sọrọ, Atiku ti ko mọgba ti omi bọ loju ẹ dupẹ lọwọ awọn eeyan naa fun ohun ijọniloju ti wọn ṣe fun un yii. O ni igba akọkọ ree ti iru nnkan bẹẹ yoo ṣẹlẹ latigba toun ti gbegba oṣelu. O ni pelu nnkan ti wọn ṣe yii, o ti fi han pe ajọṣepọ to danmọran ti wa, ati pe awọn yoo jọ ṣiṣẹ naa pọ ni pẹlu idaniloju pe awọn yoo jawe olubori nigbeyin.
O wa ro awon alatileyin e lati jade lopo yanturu lasiko ti egbe PDP yoo se pamari lati yan eni ti yoo dije loruko egbe ohun lodun 2019. O ni, “Ti a ba po daadaa wa sibi ti won yoo ti seto
ibo pamari, egbe PDP ko ni i ri ohunkohun se ju ki won gbe ipo ohun fun wa lo, ti a ba si ti gba a dajudaju, awa la maa wole sipo Aare lodun 2019.”   


Post a Comment

0 Comments