GBAJUMO

E SO FUN AMBODE KO MAA PALEMO ERU E NILE IJOBA L’ALAUSA – ALAGA ADP


Adewale Abolaji

Alaga ẹgbẹ oṣelu ADP nipinlẹ Eko, Adewale Abọlaji ti mu un da gbogbo awọn eeyan ipinlẹ naa loju pe ẹgbẹ naa ti ṣetan lati gbakoso lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina to n bọ lọdun 2019.
O sọ idaniloju yii lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ, nibi to ti fidi e mule wi pe gbogbo ọna lawọn yoo gba lati ri i pe ẹgbẹ naa mu awọn araalu kuro loko amunisin tẹgbẹ APC ko wọn si, ati pe awọn ti gbaradi fun idibo naa. O ni titi di akoko toun sọrọ yii lawọn eeyan to fi mọ awọn ọdọ atawọn obinrin fi n darapọ mọ egbe oselu ADP.
Adewale tun te siwaju pe ẹgbẹ oṣelu to wa lode yii ti da awọn araalu, wọn si tun n da wọn lọwọ bayii, Ọlọrun nikan lo so pe o le gba wọn kuro loko ẹru awọn ijoba naa. O ni, idi niyi tawọn araalu fi pinnu pe ẹgbẹ oṣelu ADP nikan lọna abayọ to le gba awọn kalẹ.
Bakan naa lo sọ pe ẹgbẹ ADP ni awọn eto to lagbara fawọn ọdọ, nitori pe awọn gan-an ni wọn n dibo ju, ohun to si ṣẹlẹ ni pe a-lo- pa-ti lawọn oloṣelu maa n fi wọn ṣe, eyi ti ko ni i waye ninu egbe oselu ADP.
O fi kun un pe, aye wa fun wọn lati jade ki wọn dije fawọn ipo to wa nilẹ, ati pe o da oun loju pe wọn yoo wọle.
Siwaju si i, o ni ko si ọdọ kankan to wa ninu ẹgbẹ naa ti yoo kabamo pe oun darapọ mọ awọn, awọn ọdọ naa si ti bẹrẹ iṣẹ lati ri i pe ninu ibo to n bọ yii, wọn ko fawọn sẹyin, bẹẹ lo tun ni awọn obinrin naa ko ni i gbẹyin ninu awọn eto wọn ninu ẹgbẹ naa.
Lori kaadi alalopẹ iyẹn PVC, Alaga naa sọ pe o fẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu ADP nikan lo n polongo ẹ fawọn araalu ju lati lọ gba a ki anfaani le wa fun wọn lati kopa ninu ibo to n bọ yii. O wa pari ọrọ ẹ pe pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, ki ẹgbẹ oṣelu APC  di ẹru wọn silẹ, nitori o da oun loju pe awọn ni yoo gbakoso Alausa lagbara Ọlọrun.


Post a Comment

0 Comments