GBAJUMO

IYA BURUKU NI AMBODE FI N JE AWON AGBALE L'EKOO- EGBE OSELU ADP

Ẹgbẹ oṣelu alatako nipinlẹ Eko, Action Democratic Party, ADP ti ke si Gomina Akinwumi Ambọde lati sanwo oṣu awọn agbalẹ oju popo ti wọn ṣe iwọde laipe yii lori bi ijoba ipinle naa se n fiya nla je won lori owo osu won.
Ninu atẹjade ti alukoro fẹgbẹ naa, Ọmọọba Adelaja Adeoye fi sita lo ti sọ pe o jẹ ẹdun ọkan bii ileeṣẹ Visionscape ati ijọba ipinlẹ Eko ṣe n ṣe awọn oṣiṣẹ naa. O ni bii igba ti wọn n fara ni awọn araalu lẹgbẹ oṣelu ADP ka a si.
Wọn fẹsun kan Gomina Ambọde lori bo ṣe gbe awọn oṣiṣẹ agbalẹ oju popo naa kuro labẹ PSP ti wọn n gbiyanju lati jẹ ki Eko wa ni imọtoto, ti wọn si gbe wọn sabẹ Visionscape ti wọn kuna patapata lori iṣakoso imọtoto nipinlẹ naa. 
Adelaja tun ṣalaye pe latigba ti Gomina ti ṣagbekalẹ ileeṣẹ tuntun naa ni idọti ti n pọ si i kaakiri ipinlẹ Eko, bẹẹ lo si jẹ pe awọn oṣiṣẹ ti wọn gba lati maa ko ilẹ ati idọti, wọn kọ, wọn ko fun wọn lowo oṣu. 
O ni itiju nla lo jẹ fun ijọba ipinlẹ Eko pe awọn agbalẹ oju popo ṣewọde lọ si Alausa pe wọn je awọn lowo oṣu to pọ. Eyi to tumọ si pe igbe aye awọn araalu ko jẹ ijọba ohun logun mo. O fi kun un pe niwon ti wọn ba ti n jẹ iru awọn eeyan bẹẹ lowo oṣu, ati pe ijọba APC ti kuna patapata nipinlẹ Eko.
Wọn nigba tileeṣẹ Visionscape ti kuna lati jẹ ki imọtoto wa nipinlẹ Eko, ohun to dara ni pe kijọba gba ise ohun lowo ileese naa, nitori inu awọn araalu ko ni i dun ki wọn maa nawo ti ko ni itumọ lori ileeṣẹ ti ko mu aṣeyọri bawon.
Wọn ti rọ ijoba Ambode l'Ekoo lati ri i pe o san gbogbo owo to jẹ awọn eeyan naa ki iderun le ba araalu.

Post a Comment

0 Comments