Bi eto idibo odun 2019 se n
sunmo etile, tawon oludije ti n lo kaakiri, Alhaji Atiku Abubakar toun naa fe
dije labe asia egbe oselu PDP ti kabamo nla lori iranlowo to se fun Asiwaju
Bola Tinubu lodun 2003.
Laipe lo soro yii lasiko to n ba awon omo egbe
oselu PDP soro, nibi to ti toro
aforiji lowo gbogbo omo egbe oselu PDP nipinle Eko pe ki won foriji oun lori
asise toun se egbe naa ko se wole ibo nipinle
naa lodun 2003.
O soro yii lakooko to n sabewo sawon omo egbe naa
nipinle Eko lori erongba e lati dije fun ipo aare labe egbe oselu naa
ninu ibo to n bo lodun 2019. Gege bo se wi, o ni bo tile je pe aare orile-ede yii toun je igbakeji e, Oloye Olusegun Obasanjo
pase foun pe koun ri i pe won gba gbogbo ile Yoruba fegbe oselu naa sugbon toun
kuna.
O ni,
nnkan to si faa nigba naa ni ajosepo to danmoran to wa laarin oun ati Asiwaju
Bola Ahmed Tinubu toun naa je gomina ipinle Eko lakooko naa.
O ni gbogbo
igba toun ba si n ro o
loun maa n kabamo pe asise nla loun se, o si je okan lara nnkan to mu
ifaseyin ba orileede yii, ti won ko fi kuro loju kan.
O so pe o se ni laaanu pe opo awon ti won je ki egbe
PDP rowo mu nile Yoruba lodun 2003 ni won ti gba akoso egbe lowo won, ti ko si
ye ko ri bee. O
wa be awon omo egbe naa pe ki won foriji oun lori nnkan toun se yii ati pe iru
e ko ni i
sele mo.
Atiku tun fi kun un pe nigba tawon gba ijoba lodun 1999, gbogbo ile Yoruba
lo ni egbe
oselu (Alliance for Democracy) n sakoso e nigba yen.
Igbakeji Aare tele lorile-ede yii salaye pe oun ati Tinubu ti n bara won bo
latinu egbe oselu SDP, PDM, nitori e loun se yonda Eko fun un nigba naa. O
ni ti ki i ba se bee ni, o rorun foun lati gba Eko lowo e, sugbon
ni bayii,
abamo nla lo je foun nitori bi won
tun ti se gba gbogbo ile Yoruba.
Okunrin naa wa so pe, “Mo
be yin ki e foriji mi, ki e si fun mi ni oore ofe mi-in. Ipinle Eko yoo sise papo pelu awon egbe oselu PDP
yooku lati gbakoso e.’
Leyin to ti se ipade po pelu awon agba ati oloye egbe
naa tan ni ofiisi egbe naa, lo tun ba gbogbo awon omo egbe soro, nibi to ti
toro fun iranlowo won lati satileyin fun un ki tikeeti lati dije naa le te e
lowo.
Lara awon to tele wa ni Otunba
Gbenga Daniel to je oga agba eto
ipolongo Atiku ati Oloye Godsday Orubebe fun
ipo Aare lodun 2019.
0 Comments