GBAJUMO

E WO FIDIO BI ERO REPETE SE YA WO ILEESE RADIO LAGELU N'IBADAN, ILEESE OKO OLOYUN LO GBE ETO ORO AJE NLA WOLU

Alh. Fatai Yusuf Oko Oloyun
Ese ko gbero laipe yii nileese radio LAGELU FM niluu Ibadan lasiko ti gbajumo sorosoro nni, Kola Olootu kede lori eto e wi pe anfaani nla ti wa fun awon araalu lati wa gbe apoti itaja (Kiosk) ileese OKO OLOYUN lofee.
Ohun ta a gbo ni pe, eeyan aadota (50) pere ni won pe ki won wa gba apoti itaja yii, sugbon bii egbelegbe lawon eeyan ya wa bii omi. Bi omode se ya wo ileese ohun lojo naa, bee lawon agbalagba paapaa da girigiri wa, ohun ti gbogbo won si n wa lojo yen ni bi won yoo se janfaani eto okoowo ti ileese Oko Oloyun gbe wo ilu Ibadan.
Ofe ni ileese to n po egboogi orisirisi to n se iwosan nla fun omo araye yii n gbe apoti ohun fun awon eeyan pelu anfaani olokan-o-jokan mi-in to le mu igbe aye irorun ba t’olori-telemu won laarin ilu.
Lara awon egboogi tileese ohun n gbe jade to gbajugbaja bayii, tawon eeyan ko le maa lo ni FIJK, HERO, WIPER, MEGATO toun naa tun gbode bayii ati orisirisi mi-in ti awon eeyan n jerii si pe ise nla ni won n se lago ara.


Post a Comment

0 Comments