Malik Ibitoye |
Alukoro f'egbe oselu PDP nipinle Ogun,
Alaaji Malik Ibitoye ti so pelu idaniloju pe egbe oselu naa ni yoo wole fun ipo
gomina lodun 2019, nitori idi eyi ki Amosun atawon eeyan e maa
di eru won sile lati kuro nile ijoba.
O soro yii lakooko to n kopa nibi iforowanilenuwo
kan, nibi
to ti fidi e mule pe
ijoba ti egbe oselu APC n dari lowo nipinle
naa lo fe buru ju, ati pe awon
araalu si ti pinnu lati fi ibo le won danu. O fi esun kan Gomina Ibikunle
Amosun lori bo se je pe opo awon ise akanse to n se lo fi si eya kan ju okan
lo, ati pe awon igberiko to ti ye ko sise le lori lo pati, ti ko si ye ko ri
bee.
Bakan naa lo tun salaye pe opo awon
igberiko lona won ti baje, tijoba to wa lode yii ko se nnkankan le lori,
eyi to si mu ki igbe aye le koko fawon olugbe ti won n gbe nibe. O tun so
siwaju pe bijoba naa se n pariwo pe eto eko je oun logun, o ni opo
awon ileewe giga ni ipo ti won wa ko derun rara.
O fi kun
un pe ibanuje okan lo je pe bijoba Gbenga Daniel se fi awon ileewe naa si lo si
wa titi
di akoko yii. O ni, lara nnkan ti Gomina
tele to wa lati inu egbe oselu PDP se lori eko ki i se kekere. O ni bo se da
ileewe Poli ICT sile lawon igun kookan nipinle Ogun,
bee lo tun ri i pe agbega ba ileewe Yunifasiti
Olabisi
Onabanjo,
eyi to je tijoba ipinle bee lo tun sagbekale Yunifasiti
mi-in,
iyen Tai Solarin to wa ni Ijebu Ode.
Bee lo so pe kekere lawon
araalu si n ri lawon ise akanse ti Onarebu Oladipupo Adebutu n se
kaakiri, ati pe bi won ba le dibo fun un ko wole
sipo gomina lodun 2019, gbogbo eeyan ni yoo je mundunmundun e daadaa.
Malik Ibitoye tun so siwaju pe
lara ise ti Ladi Adebutu to je onarebu nile igbimo asoju sofin niluu Abuja nibi
to ti n soju ekun Ikenne/Shagamu/Remo ti
se ni
fifun awon araalu ni ero amunawa ogorun-un
kaakiri ipinle Ogun, eyi ti ko ti i
sele ri.
O ni, “Awa
ti setan lati gbakoso lowo egbe oselu APC ninu ibo gomina to n bo lodun 2019,
nitori gbogbo igba lawon araalu n so pe awon fe ayipada rere, igbe aye tijoba
to wa lode yii n ko awon si ko te won lorun.o si da mi loju lodun to n bo wi pe awa
la maa gbakoso Oke- Mosan lagbara Olorun.”
Ibitoye tun so pe edun okan lo je pe
Amosun ko pese ise fawon eeyan bo ti to ati bo se ye. O ni,
bawon odo ko se nise ki i se nnkan to dara, ati pe gbogbo
e
pata ni Ladi Adebutu yoo sise le lori to ba
depo naa.
Bee lo ni oko gbese ni Amosun tun
fojoojumo ko ipinle ohun si pelu bo se n yawo, eyi ti yoo gba
opolopo odun ki won too le san an tan.
O ti ro awon eeyan ipinle Ogun lati lo ibo to n
bo fi yan Onarebu Ladi
Adebutu, omo egbe
oselu PDP sipo ki igbe
aye irorun
le fun
kaluku.
0 Comments