Akinwunmi Ambode |
Nibi inawo kan ni
won tun ti pade, Gomina Akinwunmi Ambode ati Bola Tinubu pelu awon eeyan
jankan-jankan mi-in ni won wa nibe lojo naa. Oga agba ileeefwopamo Zenith, Jim
Ovia lo se ifiliole iwe kan, bi Bola Tinubu ti soro tan, ti won ni ki Ambode
naa o wa soro, ni iyen ba fi towo-towo ati awada so wi pe, niwon igba ti Asiwaju oun ti
soro, iyen Bola Tinubu, ki loun tun fe wi mo.
Oro to so ree,
nibe gan-an lawon eeyan ti bere si gbe e kiri wi pe, o jo pe Gomina naa ti tete
n gba f’Olorun nipa bi awon omoleyin Tinubu atawon eeyan kan se gbogun ti i wi
pe ko tun ni i se ijoba Eko leekan si i.
Asiwaju Bola Tinubu atawon ti won jo wa nibe |
Lojo Aje Monde,
ana ni iroyin ohun gba igboro kan, o fe ma si iwe iroyin ti ko gbe e, ohun ti
kaluku won si fi se akole ni pe, Akinwunmi Ambode, gomina Eko ti so pe, oun ko
gbodo soro kan bayii, niwon igba ti Asiwaju Bola Tinubu ba ti soro. Bo se ti so
o lawon eeyan ti n lo oro ohun mo wahala to wa nile, nipa bi awon kan se so pe
Asiwaju Bola Tinubu ko setan lati ti i leyin mo, ati pe niwon igba ti ko ti fun
oun laaye, o je pe gomina naa ti setan lati maa palemo eru e mo.
Itumo tawon eeyan
kan ninu oselu n fun akole to gbode kan ohun niyen, se ohun ti Gomina si gba
lero ni pe, erin ko gbodo fon ki omo e naa tun fon, sugbon bi oro ohun ti jade
lenu e lawon eeyan ti sare lo o mo ohun to n sele lowo niluu Eko, ti won si n
gbe e kiri pe, o dabii eni pe Ambode ti fe maa gba f’Olorun.
Te o ba gbagbe, bi
okunrin oloselu omo Epe yii se fi ipinnu e han lati dije loruko egbe oselu APC
leekan si i lokunrin onimo nla kan, Babajide Sanwoolu, eni to ti sise kaakiri
ileefowopamo, to tun ti ba Femi Pedro ati Bola Tinubu sise papo lasiko ti won
sejoba Eko naa so pe; ipo Ambode gan an lo wu oun julo ninu ibo odun 2019.
Ambode, Ojogbon Osinbajo ati Jim Ovia to n senawo |
Bi wahala se bere
ree, paapaa bi awon kan ti won je alatileyin Bola Tinubu se duro gbon-in ti
Babajide Sanwo-Olu leyin, ti gbogbo alaga ijoba ibile idagbasoke metadinlogota
to wa l’Ekoo si so pe okunrin naa lawon n ba a lo. Pelu gbogbo aduroti ti won n
fun yii, ohun kan ti Asiwaju Bola Tinubu si tenumo ni pe, ibi ti awon agbaagba
egbe ba ti lo loun n lo, nitori awon gan-an lopo egbe, ati pe ola tiwon gan-an
loun naa fi n mi.
Nibi ti oro wa
niyen, nigba ti won si jo pade nibi apeje, ti Gomina Ambode fi oro dapara wi pe
niwon igba ti Asiwaju ti soro, ki loun tun fe so mo, nibe yen gan-an lawon
eeyan ti so pe o dabii eni pe okunrin naa ti fe gba f’Olorun oba!
Lara awon eeyan pataki
to wa nibi ifilole iwe ohun ni igbakeji aare orile-ede yii, Ojogbon Yemi Osinbajo, Akintola Willams; oga agba ileese Channels
Television, John Momoh; Tony Elumelu, Folorunsho Alakija; Alagba Christopher
Kolade; Pat Utomi ati bee bee lo.
0 Comments