GBAJUMO

YINKA RYTHMZ, OMO NIGERIA TO N GBE L’AMERIKA GBE REKOODU MEJI JADE LEEKAN NAA


Gbajugbaja olorin omo bibi orile-ede yii ni Yinka Rythmz sugbon to fi orile-ede Amerika sebugbe, okunrin naa ti gbe rekoodu nla meji jade leekan naa.
Mr Somebody bawon eeyan tun se mo on si ti pe akole awon orin mejeeji ohun ni 'Ife mi ati Telephone Conversation' Kaakiri agbaye nibi ti awon ololufe e wa ni won ti n fi awon orin tuntun naa jegbadun ara wo bayii. Ninu rekoodu Ife mi ni Yinka to fi ilu Houston sebugbe ati gbajumo olorin mi-in, Chivibes ti kopa ninu e, ati pe Samson Ohda lo dari e.
Ni ti 'Telephone Conversation', okunrin kan ti won n pe ni Pappululu lo po o po.  
Te o ba gbagbe, okan ninu awon omo agba-oje olorin fuji to ti d’oloogbe, Alaaji Rasheed Adio, eni tawon eeyan tun mo si Mr.Somebody tabi Second Barrister l'Agerige ni Yinka n se. 
Yinka ni won fi joye Apase ilu West  Coast, bee lo tun je Atolase ilu Texas. Laipe yii lo gbe Dokita Ogonna Ifeayi niyawo lorile-ede Amerika. 
Iwo naa le janfaani orin naa nipa kika a sile lori opopo to wa nisale yii.

Post a Comment

0 Comments