GBAJUMO

EDE IJEBU TO SO MI DOLOKIKI NINU SINIMA, ASIRI TO WA NIBE REE- IJEBU ONITIATA


Lara awon odomode alawada ti won n se daadaa ninu sinima Yoruba loni-in ni Olatayo Amokade, eni ti awon eeyan tun mo si Ijebu.
Ni nnkan bii odun meloo kan seyin lo bere ise sinima Yoruba lodo Muyiwa Ademola niluu Ibadan, ki oloju si too se e, Tayo ti di igi araba, paapaa latari ede abinibi e, iyen ede Ijebu to maa n so ninu ere.
Ijebu ti ba Magasinni yii soro, e maa ba wa ka lo:
ITAN SOKI NIPA MI ATAWON OBI MI
Oruko mi ni Olatayo Amokade, Mo wa lati inu ebi Toko-taya Kolawole ati Arabinrin Christianah Amokade ni ilu Ilisan Remo nipinle Ogun.
Ileewe alakoobere mi ni Wesley Primary School, leyin ti mo kuro nibe ni mo te siwaju lati kekoo si i, bi mo se wi ile eko girama.
Awa marun-un ni awon obi mi bi, emi si ni abikeyin won. Nigba ti mo pari eko girama ni Ilisan, n’Ijebu Remo, mo kuro nibe pelu erongba lati te siwaju ninu eko mi.
Sa o, lati kekere ni mo ti feran ere idaraya, bi ki n maa ko awon omode jo, ki n maa pa alo fun won, bee ni mo tun maa n dari eto lode ariya, ti maa maa pa awon eeyan lerin-in.
Inu mi ki i dun ti awon eeyan ba roju koko, mo maa n fe ki kaluku maa yo, ki agbo ariya maa dun yungba ni. Iru eda ti mo je gan-an niyen.
Ki emi naa le je eeyan, mo te siwaju ninu eko mi, mo lo sileewe The Polytechnic, n’Ibadan. Mo wa nileewe yen laarin odun 2002 si 2005, eko nipa ise iroyin ni mo ko nibe, iyen ninu ogba ileewe ohun to wa ni Eruwa.
BI MO SE YA SIDII SINIMA
Lasiko ti mo n kawe lowo ni mo ti nifee si ere ori-itage, bee lo wa lokan mi lati darapo mo awon osere tiata.
Eni ti okan mi mu julo laarin awon osere tiata nigba yen ni Muyiwa Ademola, oun gan-an loga to ko mi nise sinima yii. Lati Eruwa, nibi ti ileewe mi wa ni mo ti maa n lo kose lodo won.
Gbogbo Ojobo Tosde ati Fraide la maa n se igbaradi, iyen rihiasa nigba yen. Orisirisi idanilekoo ni won maa n fun wa, bi a se gbodo duro niwaju kamera, ati agbekale oro ti a ba dori itage tan, atawon eko mi-in lolokan-o-jokan.
Nibe yen nigba naa, mo tun ni enikan to je amugbalegbee oga wa, David Otemolu loruko won. Eni yen gan-an lo tubo mu ise yen rorun fun mi, nitori gbogbo ohun to ye ki n mo pata ni okunrin daadaa yen maa n la ye mi.
MO TUN TE SIWAJU LODO SANYERI
Nigba ti mo pari lodo Muyiwa Ademola ni nnkan bi odun meje seyin, asiko igba yen naa ni mo pari eko mi ni The Polytechnic n’Ibadan. Bi mo se digba-dagbon niyen, n ni mo ba dero Eko.
Nigba ti mo maa de Eko, awon oga mi mi-in naa ti wa l’Ekoo, iyen Olaniyi Afonja, eni tawon eeyan tun mo si Sanyeri ati Adekola Tijani, yen Kamilu Kompo. Ikorodu ni won wa, awon gan-an ni mo n ba se, odun meji gbako ni mo lo lodo Sanyeri, a jo maa n lo kaakiri ni, emi ni mo maa n gbe e kiri nigba yen, bee lo maa n so fawon eeyan wi pe won gbodo lo mi ninu ere won nigba yen.
BI EDE IJEBU TI MO N SO SE BERE GAN-AN
Ni gbogbo asiko yii, ipa manigbagbe ni Sanyeri naa ko ninu ohun ti mo je loni-in. Bee Ijebu ti mo n je yen, odo oga mi Muyiwa Ademola ni mo ti gba oruko yen.
Ere kan la fe se lodun naa lohun-un, oga mi Muyiwa ba bi mi pe se mo le so ede Egba, mo ni mi o mo on so, o ba tun bi mi wi pe eka ede Yoruba wo ni mo le so daadaa, ni mo ba so pe, mo le so ijebu die. bi mo se so lojo naa niyen, nigba ti awon eeyan si tewo gba a, bo se di omi ati eje niyen, se omo Ijebu naa kuku ni mi tele. Ijebu ti mo n so yen, idunnu nla lo n je fawon eeyan mi kaakiri agbaye, nitori won ri mi bi eni to n gbe ede naa laruge, to si n je ki won mo pe eka ede to lami-laaka ni, ni Nigeria ati kaakiri agbaye.
Ijebu yen naa ni mo so lojo naa lohun-un bi awon eeyan se gba a niyen o, ti mo si tibe dolokiki.

AWON AGBA OSERE TI MI O LE GBAGBE
Nigba ti mo sese bere, loke-loke ni mo maa n wo awon gbajumo nla nidii ise sinima bii Baba Suwe, bii Yinka Quadri, bee lo maa n wu mi nigba yen wi pe ki Olorun tie ba mi se e, ki n sere pelu awon eeyan nla yii.
Nigba akoko ti maa lanfaani lati sere papo pelu awon eeyan nla bii Yinka Quadri, Ogogo atawon mi-in, inu mi dun, ara mi ya, bee lawon gan-an gba mi niyanju wi pe, ti mo ba le tera mo on, ojo iwaju mi yoo dara nidii ohun ti mo yan laayo yii.
IYATO NLA TI BA ISE SINIMA
Iyato nla wa ninu ohun ti a n se nisinyi ati bi awon baba wa se se e tele. Nigba kan, fidio kaseeti ni a n gbe kiri, nigba to ya la so o di VCD, ohun to tun gbode bayii ni Youtube, nibe yen ni gbogbo sinima tun n lo bayii. Oju ti mo fi wo o ni pe, nibi ti olaju tun ba wa de niyen, bee ibi ti aye ba yi si, o ti di dandan ki awa naa yi sibe pelu. Igba kan VHS ni, o ya o bo si VCD, Youtube lo gbaye kan bayii. Fiimu to ba ti wu eeyan wo, ori google leeyan maa lo, to ba si ti te oruko sinima to fe, lowo kan ni. Ise olaju niyen o.
ISE SINIMA TA N SE KOJA ERE LASAN
Ko si ise ti ko ni isoro kan tabi mi-in ninu. O kan je pe nigba ti emi n kose yii, tidunnu-tidunnu ni mo fi n ko o, nitori ohun to wu mi lokan ni. Ko si ise to rorun o, awon ti won ba n wo ise sinima bii ere, o koja bee, o lawon ohun ti eeyan gbodo mo, o tun lawon nnkankan ti eeyan gbodo se. Kamera ni ede tie, bee ni ina ti won n tan si wa loju atawon ohun mi-in to wa ninu ise sinima naa ni abuda tiwon. Oro yen koja action nikan o…ohun to wa leyin efa ju eje lo, kiko ni mimo ise sinima, bi eeyan ko ba si ko o, ere lasan niru eni bee wa se.
IFE TI MO NI SI ISE SINIMA LO MU ASEYORI WA
 Awon ohun ti mo la koja, mi o ri i bi idojuko rara, nitori ohun to pada wulo fun mi daadaa ni.
Ti a ba n so nipa aseyoti ti Olorun ti jogun fun mi nidii ise yii, mo dupe wi pe, mo niyawo rere, bee ni Olorun fun mi lawon omo alalubarika pelu. Mo n seto lori iyawo, bee ni mo n se ojuse lori omo. Gbogbo ohun to ye ki eda ni, mo dupe wi pe Olorun ka emi naa ye. Ti a ba so nipa moto, a dupe, bi a si so nipa ile, eyi ti n gbiyanju e, ki Olorun ba wa yori e.
OJO OLA MI NIDII SINIMA
Iwaju ni emi Tayo Amokade n lo lojoojumo.
Ti a ba n so nipa sinima ti mo ti se, o ti fe to meedogun bayii ti mo se funra mi. lara e ni Ore meta were kan; Muniru ati Ambali, Asiko mi ni ati bee bee lo. Ti mo ba ni ki n maa so eyi ti mo ti ba awon eeyan se, mi o tie le so pe iye bayii ni mo. O po gan-an ni o. Mo dupe lowo Olorun lori bi mo se bere, nibi ta a de lode ni ati aaye giga ti o n mu mi lo.
Mo dupe lowo gbogbo awon ololufe mi, bakan naa ni mo fe ro awon eeyan to fe se sinima lati ni ifarada, ki won si ni in lokan lati kose yii doju ami. Bee ni mo tun fe ro awon eeyan ki won maa gbarukuti ise to dara, ki ojo ola orile-ede yii le tubo larinrin.

YATO SI SINIMA, ISE MI-IN TI MO TUN N SE
Ise kan ti awon eeyan tun mo mi mo daadaa ni adari eto, iyen MC, mo on se daadaa, nitori awada ti Olorun fi ke mi, bee ni mo tun mo ijo jo daadaa, gbogbo awon amuye yii, Olorun lo se o, mo si dupe lowo awon obi mi atawon ti mo ba pade nidii ise sinima, nitori igbiyanju tiwon naa ki Tayo Amokade le je eeyan, ise nla ni won se. Bee ni mo tun dupe lowo awon ololufee mi.  


Post a Comment

0 Comments