Bo tile je pe lati bi osu mefa seyin ni oludasile iwe iroyin
AWIKONKO, Ogbeni Gbenga Oladipupo ati Ogbeni Ismail Babalola topo awon eeyan mo
si Baba Yoruba ti jo wa lori oro bi idagbasoke, ilosiwaju alailegbe yoo se de
ba iroyin AWIKONKO.
Ti orisirisi ipade ati oro asoyepo si ti waye nipa bi AWIKONKO
yoo tun se gun oke agba ju ti tele lo, sugbon ni bayii, gbogbo eto lo ti pari,
ti Ogbeni Babalola ati Ogbeni Oladipupo si ti towo bo iwe adehun.
Iroyin AWIKONKO je iroyin ori ero ayelujara, to si n royin fun
igbeleke otito ati awijare, odun 2016 ni iroyin Awikonko bere lori ero
ayelujara pelu buloogi (blog), iyen www.iroyinawikonko.blogspot.com, leyin osu
mefa ni ayipada tun de, to si di website to wa lonii, www.awikonko.com.ng.
Ko din ni orileede marundinlogbon yato si Naijiria to n ka
iroyin AWIKONKO lagbaye lojoojumo, tawon eeyan si n se sadankata e. Lara awon
orileede naa ni: United Kingdom, Peru, Canada, South Africa, United States of
America, Brazil, Norway, Ghana, Benin Republic, Russia, Argentina, Germany,
England, Kenya, India, Italy, Netherland, France, Tanzania atawon min in.
Nigba to n soro nipa idi to fi gbe iroyin AWIKONKO fun Ogbeni
Ismail Babalola, Ogbeni Gbenga Oladipupo je ko di mi mo pe looto ni ko rorun
lati gbe nnkan topo awon eeyan ti mo eeyan mo sile, sugbon fun itesiwaju nipa
ise tuntun to sese gba ni.
Okunrin omo bibi ilu Abeokuta naa tun so pe lati le dojuko ise
iwe iroyin Yoruba kan to gba daadaa, ti ko si see se keeyan ko irin meji sinu
ina leekan soso, okan yoo di okan lowo, idi ni yii to fi loun gbe akoso iwe
iroyin naa sile fun eni to nigbagbo ninu e pe yoo dari e daadaa.
Oladipupo tun tesiwaju pe "Mo dupe pe nigba ti mo bere
AWIKONKO, opo awon eeyan ni won bu enu ate luu pe mi o le saseyori ninu e,
gbogbo ipa ati agbara mi ni mo sa lati le je kawon eeyan tewo gba a, ti Olorun
si gbo adura naa.
"E ma je ki n tan yin, pupo ninu awon ti won foju tembelu
mi nigba naa ni won n bebe pe awon fe ki AWIKONKO gbe iroyin awon lonii, awon
eeyan tun n gbe ipolowo fun wa, ko da a, ijoba ipinle Ogun mo iroyin AWIKONKO.
"Bi mo se n se AWIKONKO naa ni mo tun n sise fun iwe iroyin
kan ti mi o ni fe e daruko e, sugbon ko rorun lati ti irin meji bo inu ina
leekan soso, idi ni yii ti mo fi pinu lati wa eni ti yoo tesiwaju e, ti mo si
nigbagbo pe oga mi ti mo gbe isakoso e sile fun yoo sabojuto e daadaa.
"O ti le lodun merin ti mo ti mo Ogbeni Babalola, ko da a,
awon ni won ko mi ni ede Yoruba nigba ti mo je akekoo nileewe gbogbonise ti
Moshood Abiola (MAPOLY, Abeokuta). Awokose ni Ogbeni Babalola je fun mi, ti won
si ti ko ipa to joju ninu igbesi aye mi. Mi o le kabamo pe mo gbe sile fun won
nitori pe won mo tinu teyin nipa ede ati iroyin abinibi, Yoruba."
Ogbeni Babalola topo awon eeyan tun mo si Baba Yoruba nigba toun
naa n soro, o ni inu oun dun lati gbakoso iroyin AWIKONKO, bo tile je pe osu to
koja lohun, August ni eto naa ti pari, sugbon oun loun da a duro di asiko.
Babalola wa a fidi e mule pe o see se lai pe, iroyin AWIKONKO
yoo di iwe iroyin tawon eeyan yoo maa ka ninu iwe, eyi ti yoo fawon ti mo nipa
ero ayelujara lanfaani lati maa ka.
0 Comments