GBAJUMO

LONI-IN NI ALHAJI SOLAQ YOO SETO ADURA FIDAU FUN MAMA E TO DOLOOGBE




Ese ko ni i gbero loni-in, ojo Eti, ojo keji osu kokanla, bi alase ati oludari ileese Solaq Spiritual Home yoo se ko gbogbo eeyan jo lati se adura ojo mejo fun mama e, Alhaja Afusat to jade laye leni odun metadinlaadorun-un (87).
Ilu Ibafo nijoba iibile Obafemi Owode ni Alaaji Abdul-Rasheed Fasaasi, eni tawon eeyan tun SOLAQ so pe eto ohun yoo ti waye.
Ni nnkan bi ojo mejo seyin ni mama naa jade laye, ti won si ti sin in nilana esin Musulumi.
Ninu oro Solaq lo ti sapejuwe mama naa gege bi abiyamo tooto, ti igbaiyanju e lori omo ko lafiwe rara. O ni, “Titi aye la o maa ranti mama wa, nibi ti awa omo de loni-in; Olorun ni o, bee lo mo on mo fi iya to bi wa salatileyin fun wa. Abiyamo to
Oloogbe Afusat
maa n de omo ladeesi ni won. A si dupe wi pe Olorun fun won ni emi gigun, bee lawa naa gbiyanju lati toju won daadaa, bo tile je pe eyi ti awa se, ko to ida kan ninu ohun ti awon obi se fun wa, lori ki a le wa saye, ati ki a le je eeyan. Ki Olorun ba wa se alujona onidera fun Alhaja wa.” Solaq lo so bee.

Aago mewaa aaro lo so pe eto ohun yoo bere, nibi ti awon afaa ti won je gbajumo nla ninu ise Olorun yoo ti sadura fun oloogbe naa ati gbogbo omo to fi sile saye lo.
Lara awon omo to gbeyin mama yii ni Isiaka, Ramota, Alhaji Rasheed Solaq ati Rasheedat atawon iyawo, pelu awon omo omo.
Ekunrere bi eto isinku ohun ba se lo, la o fi to yin leti.



Post a Comment

0 Comments