Ese ko gbero lojo Eti, Fraide ojo keji osu
kokanla, bi alase ati oludari ileese Solaq Spiritual Home atawon ebi e se ko
gbogbo eeyan jo lati se adura ojo mejo fun mama won, Alhaja Afusat to jade laye
leni odun metadinlaadorun-un (87).
Ilu Ibafo nijoba iibile Obafemi Owode ni eto
adura ohun ti waye, nibi ti awon Alfaa nla nla ti pejo lati seto pataki ohun.
Lara ohun to tun waye lojo naa ni irun Jimo ti
won koko ki, ki adura fidau ohun too bere. Bo tile je pe ko si mosalasi Jimo
nile
ohun, sibe, won kirun jimo nibe, niwon igba ti awon Musulumi to wa nibe lojo naa ti po daadaa niye, tawon Afaa nla nla si ti wa nibe pelu.
ohun, sibe, won kirun jimo nibe, niwon igba ti awon Musulumi to wa nibe lojo naa ti po daadaa niye, tawon Afaa nla nla si ti wa nibe pelu.
Saaju ojo naa ni won ti sin mama naa nilana
esin Islam ni kete to jade laye
Ninu oro Solaq lo ti sapejuwe mama naa gege bi
abiyamo tooto, ti igbaiyanju e lori omo ko lafiwe rara. O ni, “Titi aye la o
maa ranti mama wa, nibi ti awa omo de loni-in; Olorun ni o, bee lo mo on mo fi
iya to bi wa salatileyin fun wa. Abiyamo to maa n de omo ladeesi ni won. A si
dupe wi pe Olorun fun won
ni emi gigun, bee lawa naa gbiyanju lati toju won
daadaa, bo tile je pe eyi ti awa se, ko to ida kan ninu ohun ti awon obi se fun
wa, lori ki a le wa saye, ati ki a le je eeyan. Ki Olorun ba wa se alujona
onidera fun Alhaja wa.” Solaq lo so bee.
Lara awon omo to gbeyin mama yii ni Isiaka,
Ramota, Alhaji Rasheed Solaq ati Rasheedat atawon iyawo, pelu awon omo omo.









0 Comments