GBAJUMO

IBO GOMINA-ITIJU NI JIDE SANWO-OLU ATI APC YOO BA PADE LODUN 2019- JIMI AGBAJE


Oludije fun ipo gomina l’Ekoo, Ogbeni Jimi Agbaje ti so pe, itiju ni egbe oselu APC ati Babajide Sanwo-Olu yoo ba bo nibi eto idibo gbogbo-gboo ti yoo waye lodun to n bo.
Gbajumo oloselu omo egbe PDP yii soro ohun lasiko to n ba awon ololufe e, atawon omo egbe oselu e soro nipinle Eko, nibi to ti fi erongba re han lati dije dupo gomina l’Ekoo lodun 2019.
“Alubole ni maa fi egbe oselu APC ati Babajide Sanwo-olu to fe ba mi ta kangbon se ninu ibo gomina to maa waye lodun to n bo. Ohun ti mo mo ni pe gbogbo awon eeyan ipinle Eko lo wa leyin mi, bee ni won setan lati fibo won gbe mi wole. Atileyin ti won se fun wa lodun 2015 si wa nibe, ti ko yinge, bee gege lawa naa setan lati lo anfaani ohun lodun 2019, ti a o si gba ijoba Eko, nibi tawon eeyan yoo ti lanfaani nla lati je mudun-mudun ijoba.

“Ede kan ti won n pe kiri bayii ni pe, onibaara won ni mi, nitori ti mo ti jade leemeji tele, loooto ni mo je onibara won, sugbon onibara to setan lati doba mo won lowo ni.” Jimi Agbaje lo so bee loro.
Oludije fun ipo gomina ninu egbe oselu PDP tun so pe, egbe oselu APC ti kuna patapata lori ipese ohun amayederun fun araalu. Bee gege lo ti ke si awon eeyan lati fibo won le egbe naa kuro nipo ki won si fun egbe oselu PDP lanfaani lati tuko ipinle Eko debute ayo fun teru-tomo.
Siwaju si i, o ti so pe oun ni awon ohun amuye ti o le mu idagbasoke alailegbe ba ipinle Eko ti won ba le fun oun lanfaani lati di gomina, ati pe ijoba oun ko ni i kuna lati pese ise lopo yanturu fun awon odo, eyi ti yoo fun won lanfaani lati ni ipa rere ninu idagbasoke ilu.  
Lara ohun to tun seleri e fawon eeyan Eko ni ipese eto aabo to moyan lori, bee gege lo ti so pe ijoba oun yoo seto ina monamona elegberun kan megawaati, ti yoo wa fun ipinle Eko nikan, eyi ti yoo fopin si idakureku ina oba.
Eto ilera, eko to moyan lori, atawon ohun amayederun mi-in pata ni Jimi Agbaje ti so pe oun n gbe e bo wa fawon eeyan Eko, ti won ba le fibo le APC danu, ti won si ko ibo won fun egbe oselu PDP, ti oun n dije dupo loruko asia e.  

Post a Comment

0 Comments