GBAJUMO

IKE ANOBI, OLORIN ISLAM FE SE REKODU TUNTUN *BEE LO SO OHUN TOJU OLORIN KEEKEEKE N RI


Gbogbo eto lo ti pari lori rekoodu tuntun ti gbajumo olorin esin Islam nni, Hajia Rahamat Na’Allah, eni tawon eeyan tun mo si Ike Anobi fe gbe jade.
Ninu oro odomode olorin Islam yii lo ti so pe, “O se pataki gege bi olorin ka salaye fawon eeyan iyato nla to wa ninu ipin ti a yan wa saye, ati ona ti opo n gba sina. Idi niyi, to fi ye fun gbogbo Musulumi patapata atawon elesin mi-in lati mu Olorun ni koko ninu isemi aye won.”
O fi kun oro e wi pe, ipin se pataki ninu aye eda, ati pe kaluku gbodo maa sadura ki ipin rere ti Olorun ni fun kaluku le wa si imuse.
Ike Anobi te siwaju pe, “Laipe yii ni awo orin ohun yoo jade, ise ti n lo lori e, bee lo maa mi ilu titi.”
Omo ilu Ilorin ni Hajia Rahmat Na’Allah n se, yato si Ike Anobi, oruko mi-in tawon eeyan tun mo si ni Omotaye-n-so. Ninu oro e lo ti so pe, “Mi o kose lodo enikeni, funra Olorun lo fun mi lebun orin ti mo n ko yii. Rekoodu mi akoko ni mo pe akole e ni Ori mi tete la. Ni bayii, ise ti n lo lori tuntun ti mo fe gbe jade, akole e ni Ipin ti a tun le pe ni Kadara.
Muslumi daadaa lawon obi mi, ninu e ni won bi wa si, bee ni mo si lanfaani lati kekoo nipa esin ohun, eyi to n ran mi lowo daadaa lori ise ti mo yan laayo yii.”
Nigba to n soro nipa ipenija ti awon olorin ma n koju, paapaa awon ti won ba sese n dide bo nidii ise orin, o ni, “Meloo la fe so nipa ipenija ti oju ti ri, o po repete, bee ni ko se fenu so tan. Opo ojo la maa n lo sode ti a ko ni i ri owo mu bo, adura ti a n se ni pe ki Olorun je ki awa naa ga nidii ise ta a yan laayo yii. Bee lawon maketa gan-an ti won maa n gbe orin wa jade, obe to ti jinna ni won n wa kiri, ko si eyi to fe ko owo le ise eni to sese n ji bo mo, afi ki Olorun saanu awa naa, ki a le mu oke nidii ise yii. Bakan naa ni mi o le gbagbe ojo ti mo koko mu ero agbagbe lowo, iyen Micro-phone ti mo fe korin loju agbo, gbii-gbii bayii laya mi n ja, sugbon pelu asde Olorun, irorun lo pada ja si.

“Ni bayii, o ti fe to odun mewaa ti mo ti mu orin kiko bii ise. Ileekewu Markaz Zakofa ni Iyana-Ipaja ni ebun yen ti koko jeyo, Afaa mi nigba yen, mo lero wi pe nise ni won wo mo mi, ti won ko feran mi. Awon ni won koko ri ebun orin yen lara mi, bee ni won sa maa n fe ki n korin ni gbogbo igba ti a ba ti ni aseye pataki kan nileekewu. Wahala ni mo ro pe won n fun mi nigba yen, sugbon loni-in, igbiyanju yen lo di igi ola fun mi loni-in, ti emi naa fi deni tawon eeyan mo bayii. Bee ni mo ti di aridunnu nla fun Afaa mi paapaa.”



Post a Comment

0 Comments