GBAJUMO

EBI ELEJIGBO NI KI HAFEEZ BADRU TELE ASE ILE EJO *KO YE PE ARA E NI OBA LANGBASA MO

Hafeez Olakunle Badru

Ki alaafia le joba niluu Langbasa nijoba ibile Eti-Osa nipinle Eko, molebi Elejigbo ti ro Ogbeni Hafeez Olakunle Badru lati tele ase ile-ejo giga; ko ye pe ara e ni oba ilu naa gege bi ile-ejo se pa a lase.
Ninu alaye ti ebi Elejigbo se fun magasinni yii ni won ti fidi e mule wi pe, o se pataki ki okunrin to wa nipo oba ilu naa bayii tele ase ile-ejo gege bi Adajo A.J Bashua ti ile-ejo giga Eko ni ekun Epe, iyen Epe Judicial Division se pa a lase.
Lara eri ti won fi sowo si Magasinni yii ni iwe apileko ti ile-ejo naa fi gbe idajo ohun kale, ninu eyi ti Adajo Bashua ti so pe, ki Hafeez Olakunle Badru ye pe ara e ni oba ilu Lagbansa, tabi se awon ojuse kankan to ba je mo ojuse oba ninu ilu naa titi ti ile-ejo yoo fi sedajo to ye lori ejo ti won pe oun atawon kan lori eni ti ipo oba ilu naa to si gan-an.
Awon ebi Elejigbo fi kun un pe, “Ebi to nilari ni wa, bee la o setan lati fa wahala kankan to le ko idaamu ba ilu Langbasa atawon eeyan e. Alaafia ati ilosiwaju ilu yen lo je wa logun, fun idi eyi, a ro Ogbeni Hafeez Olakunle Badru ko tele ase ile-ejo ko ye pe ara e ni oba ilu yii titi ti ejo yoo fi pari, ti kaluku yoo mo ibi to n lo.” 
Te o ba gbagbe, ile-ejo ni ebi Elejigbo ti ilu Langbasa ko ara won lo lori eni to letoo si ipo oba ilu naa. Awon eeyan wonyi; Omooba Kola Balogun; Omooba Musibau Adebayo Kilani; Omooba Alamu Shonibare, Omooba-binrin Abosede Dawodu, Omooba Rasaq Oluwa ni won gba ile-ejo lo, won ni Hafeez Olakunle Badru to wa lori ipo naa ko ye nibe, ati pe ile-ejo gbodo yo o ni
.
Awon eeyan ati ileese ijoba ti won pe lejo lori oro ohun niwonyi; Ogbeni Salimon Gbadebo Anofiu Adesanya, Waliu Ademola Hassan, Ligali Balogun; Saheed Hassan, igbimo loba-loba ijoba ibile Eti-Osa; Olori akowe agba nileese ijoba to n ri si oro ijoba ibile l’Ekoo; Adajo agba l’Ekoo, gomina ipinle Eko, Wasiu Elegbeleye , Shakiru Falana Ayeni, Samodu Jimoh Abdullahi.
Ejo naa si wa niwaju Adajo agba A.J Bashua ti ile=ejo giga ipinle Eko to wa niluu Epe.



Post a Comment

0 Comments