GBAJUMO

LOJO TI LAHAOLA SALASHI GBE OYE TI IBA GANI ADAMS FUN UN LO KI OLUPAKO SHAARE *GBOGBO ILU MI TITI


Pelu idunnu nla lawon omobibi ilu Shaare atawon ti won n gbe ninu ilu ohun nijoba ibile Ifelodun ni Kwara fi pade Alhaaji Yakub Adeshina Babatunde, eni tawon eeyan tun mo si Lahaola Salashi lasiko to wo ilu abinibi e, pelu oye nla ti Iba Gani Adams fun un.
Ohun ta a gbo ni pe Kabiesi ilu e, Oba Abubakar Garba Dosunmu, Olupako ilu Shaare ni Akogun Aare Ona Kakanfo ati Yeye Akogun Aare Ona Kakanfo ile Yoruba gbe oye lo ki laafin oba.
Pelu moto tuntun, Landrover Jeep ni okunrin gbajumo nla nidii isegun ibile, bee lo tun je oludasile ile eko Adeshina College of Education to wa niluu Shaare gbe wo ilu abinibi re, ati pe tilu-tifon gan an ni won fi tele e de aafin.
Bi iroyin ti se kan wi pe Akogun Aare Ona Kakanfo pelu awon molebi e ti de saarin ilu lawon omo ilu naa ti won ko raaye ba a wa si Eko lati wa joye ohun ti n mu aso, tawon kan n sare mu fila ati gele lati foju kan omo Adeshina to mu ire nla wolu Shaare wa leekan si i.
Bi arugbo se n lo, bee lawon odo atawon omo keekeeke paapaa niluu fe wo ola nla ti ilu ohun tun ko bayii latari isel nla ti Iba Gani Adams, Aare Ona Kakanfo ile Yoruba sese gbe le omo won lowo.

Laafin Olupako Shaare ni Kabiesi ti wure fun oun ati iyawo e, atawon molebi e lapapo pelu gbogbo ilu; ti Oba Garuba Dosunmu si dupe lowo oludasile ileewe Adeshina College of Education ku ise takun-takun to n se, paapaa bo se n fojoojumo ko ire wolu ohun wa loju emi e.
Te o ba gbagbe, Olupako Shaare gan-an lo ti koko fi Lahaola Salashi je Aare Adimula. Lojo naa, oba alaye to wo ilu naa wa ko niye, bee lawon eeyan pataki atawon saraki-saraki kaakiri ile Yoruba ko lonka. Ninu won gan-an ni Iba Gani Adams, Aare Ona Kakanfo ile Yoruba wa, ti ilu si n ro kekeke fun ayeye pataki yii.

Akogun Aare Ona Kakanfo ile Yoruba, Oloye Yakub Adeshina ti so pe, ilosiwaju ile Yoruba lo je oun logun o, ati pe lasiko ti oun joye yii, opolopo ilosiwaju ni yoo maa sele ni gbogbo ilekile ti se ile Yoruba ati Nigeria lapapo.         

Post a Comment

0 Comments