
Ninu oro okan lara oludasile
egbe naa, Omooba Aderounmu Kazeem lo ti so pe, “Ohun kan pataki to mu wa da egbe
yii sile ni bi ede abinibi wa; ti a fi n gbe iroyin sita ko se ni i parun, ti igbelaruge
nla yoo tubo de ba e, ti awa ti a fi n gbe iroyin jade paapaa yoo samulo e lona
ti yoo fiwa han gege bi omoluabi ti iran Yoruba n se.”
Aderounmu, eni ti se oludasile,
Magasinni Alore fi kun un wi pe, ona kan pataki ti a tun le ko awon eeyan ni
ede abinibi wa ni gbigbe iroyin sita pelu ede ohun, eyi ti yoo fun won lanfaani
lati maa pade awon ewa ede lorisirisi ninu iroyin ti won ba n ka, ti yoo si tun
je akagbadun fun won paapaa.
Lara awon ileese iroyin ti won wa
lori ero alatagba ti won je omo egbe yii ni, Iroyin Ojutole; Bo Se Ri; Awikonko,
Magasinni Alore; Magasinni Asejere atawon mi-in bakan naa.
Egbe yii ti wa fidi e
mule wi pe, gbogbo ilana to to, to si ba eto iroyin yii mu ni awon omo egbe
naa n tele ninu ojuse won, ati pe ilosiwaju iran Yoruba ati orile-ede yii
lapapo gan-an lo je awon logun nipa lilo ede Yoruba lati fi gbe ojulowo iroyin jade.
0 Comments