GBAJUMO

IBO KU SI DEDE: EGBE AJORO OMO YORUBA PE IPADE *WON LAWON FE KEDE ENI TO YORUBA GBODO DIBO FUN

Bo se ku dede ki eto idibo bere ni Nigeria, egbe Ajoro Omo Oduduwa ti pe ipade awon omo egbe naa, nibi ti won yoo ti fenuko lori eni ti awon Yoruba yoo tele ninu ibi to n bo yii.
Won ti ni Satide ojo Abameta to n bo yii ni ipade apapo egbe AJORO OMO ODUDUWA eleekeje iru e yoo tun waye nIluu Ibadan nipinle Oyo.
Ninu atejade ti olori egbe naa fi sowo si wa, Ogbeni Tunde Balogun lo ti so pe Landlord Association Villa, eyi to wa ni Papa Eleye olomi n’Ibadan leto ohun yoo ti waye, bere laago mewaa aaro.
Siwaju si i, o ti so pe lara koko ohun ti won yoo so lojo naa ni oro nipa eto idibo to n bo, ati eni ti iran Yoruba gbodo dibo won fun gan an.
Ninu oro e naa lo ti fi kun un pe egbe AJORO OMO ODUDUWA ki i se egbe oloselu, sugbon oro to ba kan gbogbo omo Yoruba je ohun kan pataki ti won mu gege bi ojuse ninu egbe naa.
Bee gege lo fi kun un pe kaakiri gbogbo ibi ti awon omo Oduduwa wa ni owoja egbe ohun de.


Post a Comment

0 Comments