Nibi ayeye ojoobi odun mejilelogorin (82) ti Oloye Olusegun
Obasanjo se loro ohun ti waye loni-in, bi awada lawon eeyan koko pe e, sugbon bi
Alake se so o ni Obasanjo ti fun kabiesi lesi pada, bee oro Buhari gan-an lo fe
da nnkan sile laarin won.
Alake ile Egba, ninu oro iyanju e si Oloye Olusegun Obasanjo
lo ti ro o wi pe ko fi Aare Buhari lorun sile, ki baba naa se pelepele nitori
arugbo ara ti de.
O ni, “Fun opolopo odun ni Oloye Olusegun Obasanjo ti fira e
han gege bi jagunjagun, to si je akikanju nla, sugbon yoo dara ti Obasanjo ba
le ti ida re bo ako, ki o sinmi ogun. Dipo atako. Alake so pe, “Mi o ba ro yin
ki e wa nipo eni ti yoo maa fun kaluku lamoran, ti e o si maa fi ojo ale yin
yii sinmi dipo atako. E fi oga mi lorun sile (Aare Buhari), e ye satako e mo,
asiko isinimi le wa bayii.”
Bi Alake ile Egba se soro yii tan ni Oloye Olusegun Obasanjo
ti han an, ohun ti Ebora Owu si so ni pe, oun ko ni isoro kankan pelu Aare
Buhari, bi ko se pe ki igbe aye irorun wa fun gbogbo omo Nigeria.
Obasanjo fi kun un wi pe, “Ni Nigeria loni-in ko si eni to
ti i pe lori aga isakoso Nigeria bi emi Obasanjo, mo lo saa ijoba oloogun, bee
ni mo tun lo ti alagbada, fun idi eyi, iriri sagba ogbon, ti mo ba n pariwo tabi pe akiyesi ijoba kan si
ibi to ba ku die kaato si, mo mo ohun ti mo n so daadaa. Nitori ijoba orile-ede
ye mi daadaa, koda ko je aburo mi, tabi omo iya mi lo wa nipo, ti ko ba to o bo
se ye, o ti di dandan ki n pe akiyesi e si i.
“Kabiesi, e ba mi so fun oga yin, ko fi emi naa lorun sile,
ko si se ohun ti araalu n fe, oga lo je si yin, bee omoleyin temi ni, ohun to
si ye fun un ni pe, o gbodo maa gboro si asiwaju e lenu, nitori asaaju e lemi n
se lojo gbogbo.
“Fun idi eyi, e so fun oga yin ko seto ijoba to dara, ti o ba
ti se e, ko seni kan to maa gbo ariwo kan bayii lenu mi mo.”
Niluu Abeokuta; niyara ikawe nla, iyen Obasanjo Presidential Library
leto ohun ti waye loni-in ojo Isegun.
Te o ba gbagbe, soja ni Oba Alake ile Egba nigba kan ri ko too
di oba alaye, bee gege lo ti figba kan je okan lara awon omoleyin Aare Muhammed
Buhari lasiko igba toun naa wa nipo olori orile-ede yii laarin odun 1984 si
1985.


0 Comments