Okan lara awon osise Alhaji Muhammd Buhari, eni ti se Aare
orile-ede yii ni Iba Gani Adams pade laipe yii, Femi Adeshina loruko okunrin
naa n je, gbajugbaja oniroyin ni, bee lawon eeyan feran e daadaa, ti won si maa
n gbadun ohun to ba ko sinu iwe iroyin.
Osise ileese iwe iroyin The Sun ni, ko too gba ise lowo awon
Buhari. Nibi ti won ti pade ohun; nibi apejopo kan niluu Ikeja l’Ekoo ni, bee
gege ni Gomina Kayode Fayemi naa wa nibe pelu.
Nibe ni Ogbeni Femi Adeshina ti lanu koto o, ohun ti oga awon
oniroyin yii si so ni pe, “A feni ti ko ba loju, tabi to ti pinnu lokan ara e wi pe oun ko setan lati ri ohun rere kankan
ninu ijoba Buhari yii ni yoo so wi pe, ijoba naa ko ti i mu ayipada rere ba
orile-ede Nigeria atawon eeyan e.
O ni, “Lorile-ede yii loni-in, awa naa ti n fi nnkan ranse soke
okun, eyi to fihan wi pe a ti ni in lopo yanturu, ki a too le maa taari e soke
okun.
Adeshina so pe eka idokoowo wa ti ru gogo si i paapaa bi o ti se
foju han nipari odun 2017, ati pe ileese ipin idokoowo Nigeria gan-an lo fese mule
julo lagbaye. Bakan naa lo tun so pe, ileese to n ri si owo ori gbigba tun ti ni
milionu marun-un awon to n sanwo ori si apo ijoba bayii yato si ti tele.
Bee gege lo tun so pe owo tijoba apapo ti na lori ohun
amayederun fe to tirilionu meta naira (N2.7tn) O wa kadii oro ohun nile wi pe, “Ti
eeyan ba so pe oun ko setan lati ri ohun rere ti enikan n se, koda ki tohun ma
ya afoju, ki won si maa fi awon ohun meremere ti eni yen n se han an, sibe yoo
so pe oun ko ri naa ni.”
Oro to so ree, nigba ti Aare Ona Kakanfo ile Yoruba, Iba, Gani Adams naa si gba
ero agbagbe, nise lo koju si Femi Adesina, eni ti se osise Aare Buhari, o si so
fun un wi pe, “Ti e ba pada si Abuja lodo Buhari, e so fun won wi pe ebi n pa
wa, iya gidi n je omo Nigeria.”
Iba te siwaju wi pe, loooto ni agbekale yin dara, bee gege le je
olooto eeyan, sugbon pelu awon alaye te e se kale yii, ohun to dara ju ni ki
awon eeyan to wa lese-kuku, iyen awon mekunnu, o ye ki won le jegbadun ijoba to
wa lode yii. Kaakiri agbaye ni mo ti lo, orile-ede ti mo ti de yoo le ni orile-ede
merindinlaadota (46) bee ni mo mo ohun meremere tawon to n se ijoba won lawon
ibi ta a lo yii n gbe se fawon eeyan won.
Ohun to ye fawon eeyan ni ki won ri ipa ijoba lara won, loju won
ati ninu aye won, ki i se ki won maa ka a ninu iwe iroyin tabi gbo o lasan.
Ohun to ye ki won o mo ninu ile ati lodede won ni.
Iba fi kun oro e wi pe, nigba ti Ogbeni Femi
Adeshina n soro, nise loro ohun n ya oun lenu, nitori eni ti oun mo daadaa gege
bi ojulowo oniroyin ni, ti awon eeyan maa n feran lati ka abala iroyin e ninu
iwe iroyin Sun, sugbon oro to so yii fi i han gege bi agbefoba, sugbon to ba ti pada si
Abuja, o ni, “E so fun Buhari wi pe ilu ko fara ro, ebi n pa awon eeyan gidigidi.”|
0 Comments