GBAJUMO

NITORI RUKA GAWAT: ALASE OKIKI FILMS, SUNDAY ESAN TI SORO O!


SUNDAY ESAN, eni ti se alase ati oludari ileese Okiki Films & Music ti so pe rekoodu tuntun ti Alhaja Rukayat Gawat- Oyefeso  fe gbe jade eyi to pe akole e ni OGO TUNTUN yoo milu titi.
Okiki ninu oro e so pe, “Rekoodu yen ti fe pari o, Walahi, Queen of Islamic Music ati Sheikha of Music lapapo ti n se rekoodu, eyi to fe gbe jade yii, ara oto ni. Awon ilu nla nla meje otooto lati ya fidio orin ohun, bee awon akosemose ti won mo nipa ka ya fidio, ka dari e daadaa meta otooto la gba. Ogo Tuntun, rekoodu nla ti yoo milu titi ni, eyi to fihan wi pe lojoojumo ni Alhaja Ruka Gawat n te siwaju, ati pe nibi ti akorin nla yii n mu orin Islam lo, ibi giga ni.”
Ohun ti Sunday Esan so ree, bee ni Rukayat Gawat-Oyefeso naa ti so pe, eyi ti oun fe gbe jade yii, o ti di dandan ko milu titi, ati pe ni gbogbo gba loun n dupe lowo Olorun fun ajosepo alalubarika to n waye laarin oun ati ileese OKIKI FILMS AND MUSIC, eyi ti Oloye Sunday Esan je oga won nibe.
Bee loun naa so pe, OGO TUNTUN, rekoodu nla kan ti gbogbo eeyan gbodo ni nile ni.

Post a Comment

0 Comments