GBAJUMO

IKE ANOBI, GBAJUMO OLORIN ISLAM SOJOOBI, BEE LO RO GBOGBO MUSULUMI LATI GBADURA FUN NIGERIA


HAJIA Rahamat Na’Allah, eni tawon eeyan tun mo si Ike Anobi ti dupe lowo awon ololufe e, paapaa awon Ike Anobi Fans Club lori bi won ti seye nla fun un lasiko ti ayeye ojoobi e waye lana-an.
Ninu iforowero to se pelu iko akoroyin wa lo ti fidi e mule wi pe, “Ohun iwuri lo je fun mi wi pe awon ololufe mi fi ife nla han si mi, paapaa lasiko ti ojoobi mi waye. Mo dupe lowo won, bee ni mo be Olorun ki o je ki egbe naa maa te siwaju, ki gbogbo wa pata maa ri ohun rere ba ara wa se.”
Ninu oro e naa lo ti so pe, ise n lo lori rekoodu tuntun ti oun fe gbe jade, eyi to pe akole e ni Ipin, eyi to ni se pelu atiwaye gbogbo eda pata.
Bakan naa lo so pe orisirisi eto ni oun ni lodun yii ti oun fe se, eyi ti awon ololufe orin oun, Ike Anobi Fans Club naa yoo nipa nla ti won maa ko.
Hajia Rahamat ti wa ro gbogbo Musulumi aye pata lati lo asiko yii fi wa ojuure Olorun, ki won si toro ilosiwaju nla fun orile-ede Nigeria, ki ara le ro kaluku.



Post a Comment

0 Comments