…Bee lo so June 12 di ayajo ojo inoba
tiwa-n-tiwa
Iroyin yajoyajo to wa nita bayii ni pe Aare Muhammad Buhari ti
kede ojo kejila osu kefa gege bi ayajo ijoba tiwa-n-tiwa, bee lo tun fun
Oloogbe ni oye GCFR, oye to ga julo, ti won maa n fun awon Aare orile-ede.
Yato si okunrin oloselu omo ilu Abeokuta yii to dije dupo Aare
orile-ede yii lodun 1993, nibi ti eeyan bii milionu merinla ti dibo fun un ti
opo omo orile-ede yii si gbagbo pe oun lo jawe olubori ninu ibo ohun.
Bo tile je pe egbe oselu SDP ti Abiola ati amugbalegbe e,
Babagana Kingibe ti dije loruko e, sibe okunrin aloku soja to wa lori ipo
nigba naa, Ogagun Ibrahim Babangida fagile esi ibo ohun, isele ohun lo gbe
Abiola dogba ewon, nibi to pada ku si leyin odun merin to ti wa nibe lasiko
ijoba Sanni Abacha.
Ni bayii, Aare Muhammad Buhari ti so pe ojo kejila osu kefa la o
maa pe lojo ijoba tiwa-n-tiwa bayii, ati pe Oloogbe MKO Abiola ati amugbalegbe
e, Babagana Kingibe ye leni aponle, nitori awon ni won jawe olubori, ti won so
fi idi Bashir Tofa ti egbe oselu NRC janle
Oye GCFR ni won fun Oloogbe MKO Abiola, nigba ti won fun
Babagana Kingibe ni oye GCON.
Oloogbe GANI Fawehinmi naa ko sai gba oye tuntun bo tile je
akoni amofin naa ko si laye Mo.oye GCON ni won fun oun naa pelu.
0 Comments