GBAJUMO

NIB ISOJI APOTI ERI, OLORUN TI SELERI LATI SO OPO AGAN DOLOMO- WOLII TUNMISE

Ijo Holy Michael Spiritual Church of Christ, Ori Oke Bamise, Odo Mefi n’Ijebu Ife ti gbe akanse isoji olojo meje kale, fun itusile ati idande awon eeyan, paapaa awon to n woju Oluwa fun omo.
Ninu oro Oluso-Aguntan ijo naa, Prophet Dr. Tunmise, eni tawon eeyan tun mo si Ase Kiki oro, Oro kiki ase, lo ti so pe, “Nibi iwole-majemu ajodun oba eri onimajemu olojo meje ti yoo bere ni ojo ketadinlogbon, osu yii ti gbigbe apoti Oba eri onimajemu jade yoo je ojo kin-in-ni osu kejla odun yii, Oluwa Olorun oba eri onimajemu eri-bamise apata - jinbu arara aja arara mi mi ti seleri lati se ise ami ati ise iyanu ninu igbesi aye gbogbo eniyan; paapaa julo gbogbo awon obinrin to ba n woju Olorun fun omo bibi.”

O fi kun un pe eto ohun yoo waye labe akoso Wolii Agba, Snr. Prophetess Oluwakemi Ajayi, eni ti se oludasile ijo Holy Michael, Eribamise Apata 1. Ojo meje gbako lo ni won yoo fi se e, nibi ti awon to n woju Oluwa latijo to ti pe fun omo yoo ti ba Olorun Alaaye pade, ti awon naa yoo dolomo.

O ni, “Eri to daju wa wi pe Oluwa setan lati dun awon eeyan e ninu, ojo meje la o fi se isin isoji yii pelu aawe ati adura, nibe yen gan-an lawon eeyan yoo ti gba itura, paapaa awon eni ti ogun aye n ba ja, bee lawon to n wa aanu yoo ri i gba, ti ibukun alailegbe yoo ba won lo sile. 
Wolii soosi Ori oke Eribamise, ile ijoisn tawon eeyan tun mo si Jinbu Arara Aja arara mimi ti so pe, Olorun setan lati mu inu awon eeyan re dun, paapaa bi odun se n pari lo yii, ati pe anfaani nla ni ipade ipago olojo meji ohun yoo je fun gbogbo eni to ba lanfaani lati wa. Nibi ti e o ti pade baba wa,  Primate Oba Odunowo R. Abiodun, eni tawon eeyan tun mo si Ferigbade1, eni ti yoo fi ounje emi bo wa.

“Fun gbogbo awon to ba fe wa darapo mo wa,  Lati Ijebu-ode ni won yoo ti wo Keke Marwa to n lo si Ijebu-Ife, ti won ba de Ijebu-Ife, won a duro ni gareeji  Itawade, nibe ni won a ti gun okada to n lo si  Odo-Mefi. Bakan naa ni won le pe awon nomba yii: 08109244642  tabi 09031530288.

Primate Oba Odunowo R. Abiodun

Post a Comment

0 Comments