...WON LAWON YOO DOJUTI FAYOSE NI SATIDE
Bo tile je pe ariwo ti okan
lara awon oloselu nipinle Ekiti, Seneto Femi Ojudu koko pa laaaro oni ni pe, gomina
ipinle Ekiti, Ayodele Fayose n wa gbogbo ona lati gbegi dina eto ipolonogo ti Aare
Muhammed Buhari fe se nipinle ohun, sibe wamuwamu lese awon omo egbe oselu ohun
pe, ti omilegbe eeyan si jade repete.
Lori ero alatagba e, iyen Facebook page lo ko o si laaaro yii nibi to ti so pe, Fayose ti pase fawon onimoto atawon oloja ki kaluku jokoo sile e, ki won ma jade ki eto ipolongo ti aare atawon omo egbe oselu APC fe se loni-in nipinle Ekiti le fori sapon.
Wamuwamu lese awon omo egbe oselu APC pe, o fe ma si gomina ipinle ti egbe oselu APC n dari ti ko si nibe loni-in. Lara awon gomina ohun ni Ibikunle Amosun lati Ogun, Abiola Ajimobi, Azeez Yari lati Zamfara, Rotimi Akeredolu lati Ondo, Yahyah Bello lati Kogi, Rauf Aregbesola lati Osun atawon gomina mi-in.
Bee lawon asaaju egbe ohun,
Bisi Akande, Abike Dabiri, Babatunde Fashola, Chris Ngige, Adams Oshiomhole
atawon mi-in ninu egbe naa.
O fe ma si gomina ti ko soro
nibe lojo naa, bee ni Asiwaju Bola Tinubu ninu oro e sapejuwe egbe APC gege bi
egbe ti yoo tubo mu ilosiwaju ba aaralu.
Ninu oro e naa lo ti bu enu ate
lu aare orile-ede yii tele, Aare Obasanjo lori bo se n bu enu ate lu Aare
Buhari. O ni, “Ile ifopo meta ni Buhari ti ko fun wa lorile-ede yii, sugbon kin
ni Baba se, dipo e nise ni won fe gbe e ta!
“Ijoba wa, a setan lati mu irorun ba araalu, bee lojo Satide, a fe ki e jade daadaa lati wa dibo yan ayanfe ti yoo mu ilosiwaju ba yin daadaa.”
Tinubu te siwaju pe, ki i se pe ise bo lowo Fayemi niluu Abuja lo se wa gbe apoti ibo, o ni okunrin naa fe daadaa fun awon eeyan Ekiti ni, ati pe ilosiwaju daadaa ni yoo tubo mu ba awon eeyan ipinle ohun.
Ninu oro Kayode Fayemi ti se oludije loruko egbe naa, o dupe lowo gbogbo awon ti won jo seto idibo pamari, o ni, “Gbogbo won pata ni won wa nibi loni-in, ohun to si je won logun ni bi a o se jo le jegudujera lo. Ero egbe oselu PDP ni pe eto ipolongo yii ko ni i waye loni-in, nitori e ni won se pase ki moto ma rin, ti won tun ni ki awon oloja ma jade, sugbon bi gbogbo eyin eeyan Ekiti se jade loni-in, o fi han pe, ilosiwaju gidi le n wa, ati pe eni ileele patapata ni Fayose, ki i se eeyan rere rara.”
O fi kun un pe ise ti oun se tele gan-an ni yoo satileyin foun lati pada sipo ohun, nitori ise gidi loun se lasiko naa, ti ko si fe si ilu kan ti ijoba oun ko fowo ikosiwaju kan lasiko naa.
O so pe, “Ki i se pe ijoba Buhari le mi lenu ise, lasiko ti ko fe wa gbegba gomina paapaa, Aare Buhari ko fe ki n lo, nise ni mo bebe wi pe ki won je ki n lo gba awon eeyan mi sile lowo iya ti Fayose fi n je won. Ohun ti mo gbe wa ni ilosiwaju, yoo si ba gbogbo ara Ekiti.”
Ninu oro Aare Buhari lo ti salaye orisirisi ise ti ijoba apapo labe akoso e ti se fun ilosiwaju ati imayederun awon eeyan orile-ede yii, paapaa fawon eeyan Ekiti.
Buhari ti ro awon eeyan Ekiti lati dibo fun Kayode Fayemi, ki won ma je ki enikeni fi buredi ko won lobe.
0 Comments