![]() |
Oloogbe Aborisade |
Ninu ibanuje nla lawon omo egbe oselu People's Democratic Party (PDP), eka Apapa nipinle Eko wa bayii lori iku ojiji to pa alaga won lagbegbe ohun, iyen Omooba Niyi Aborishade.
Gege bi alaye ti okan lara awon omo egbe naa se fun Magasinni yii o ni, “Ipade kan ni won lo se lagbegbe Eti-Osa l’Ekoo lati fi yanju aawo to n waye laarin awon omo egbe.
Nibi ipade ohun ni won wa lowo, ti won n reti alaga egbe naa l’Ekoo, iyen Onarebu Moshood Adegoke Salvaddor. Won ni bo se de, bee lawon toogi oloselu kan yawo ibe, ki oloju si too se e, gbogbo awon alaga ti won wa nibe pata ni won fi ibon le danu, ti won si koju si Aborisade ni tie. Eni to ba wa soro yii so pe, “Nise ni won da a kunle bii eran, ti won si yinbon lu u. Ninu agbara eje lo wa ti awon yen fi ba tiwon lo”
O ni, lojuese ni won sare gbe e digbadigba lo si osibitu First Consultant l’Obalende sugbon ki won too le setoju e, elemi-in ti gba a. Bi Omooba Niyi Aborisade se dagbere faye niyen.
Sa o, alaga egbe PDP l'Ekoo ti soro, Ogbeni Salvaddor, o ni, ohun iyalenu lo je nigba ti mo gbo pe won yinbon pa alaga egbe oselu wa nijoba ibile Apapa Iganmu. Bee ohun to ya mi lenu ni ibeere ti e bi mi nitori pe mi o ko toogi kankan kaakiri, awon eso Civil Defence merin ni won n tele mi kiri, awon gan an ni won sare gbe mi kuro nibe nigba ti wahala be sile lojo yen, mo ti kuro nibe tan ki n too maa gbo pe won yinbon paayan. Ohun ibanuje lo je."
O fi kun un pe aarin akowe egbe naa, Orioye ati alaga egbe naa nijoba ibile, iyen Fasasi ni won jo n fa oro mora won lowo, ati pe ki oloju too se e, won ti bere si ju aga, nibe gan-an lawon eso alaabo oun ti sare gbe oun kuro nibe.
Salvaddor so pe, "Saaju ki a too debe lojo yen lati lo si Epe, bee la de Ibeju/Lekki naa ki a too dari si Eti-osa, tijo-tilu ni won fi pade wa. Ko sija rara, bi oro se wa di bayii, Olorun nikan lo ye. Mo si fe ki awon omo egbe wa gba alaafia laaye, ohun aburu ni o, ki Olorun ba mi ro awon ebi e loju ati gbogbo omo egbe wa lapapo."
![]() |
Oku Aborisade ree |
0 Comments