Bi omode ni Fayose bu sekun nita gbangba pelu bandeeji lorun, ohun kan to si tenu mo ni
pe ninu irora nla loun wa, ati pe emi oun ko de mo nipinle Ekiti.”
Fayose ninu alaye to se fawon oniroyin pelu
omije loju lo ti so pe, “Ti aburu kan ba sele si mi, oga agba ileese olopaa ni
ke e bi leeere. Loni-in, ohun nla lo sele si mi, Olopaa fo mi leti, won yinbon
lu mi. Olorun ni ko pa mi o, orun mi ti e n wo yii ko see yin rara, ninu irora
nla gan-an ni mo wa bayii.”
Bee lo tun bu sekun, to si ko sinu moto kan,
ti won si gbe e kuro ni gbagede ti won ti lo sepolongo ibo ni imura sile fun
ibo to fe waye lojo Satide.
Saaju ki Fayose too bu sigbe nita gbangba lo
ti koko ba awon omo egbe oselu e soro, nibi to ti fesun kan oga olopaa wi pe
oun ni awon egbe oselu APC n lo lati fi ko ipinle Ekiti sinu idaamu. Fayose wa ro
awon omo egbe oselu PDP lati duro sinsin, ki won ma mikan rara. O ni, “Ninu ihahilo nipinle Ekiti wa bayii, mo n fi
asiko yii ke si ajo orile-ede agbaye ki won wa gba wa ni Ekiti, emi awon eeyan
ko de mo nipinle yii, nise ni won n ko awon omo egbe oselu PDP satimole, ti won
n da awon tisa laamu. Ti awon olopaa ba le se emi gomina nisekuse bayii, a je pe
emi awon talika paapaa ko de mo nipinle yii. Mo fe ki eyin eeyan mi duro
sinsin, e je ka duro ti ibo to n bo yii, ki a duro pelu Eleka ki o le jawe
olubori.”
Saaju ki gomina to ba awon oniroyin
soro lawon amugbalegbe e ti soro, ohun ti won si so ni pe, nise lawon olopaa
kan yalu ile ijoba, ti won ju kemika tajutaju lu u. Won ni nise ni Fayose daku,
ti won si se okunrin oloselu naa nisekuse.
0 Comments