![]() |
Oloogbe Adeoye Iyanda |
Gbogbo eto lo ti pari lori isinku Alagba Michael Adeoye
Iyanda, eni to jade laye lojo Isegun, Tusde to koja leyin aisan ranpe.
Ninu atejade ti gbajumo oniroyin nni, Femi Iyanda, eni ti se
okan lara awon omo oloogbe fi sowo si Magasinni yii lo ti so pe, Tosde ose yii
ni eto isinku yoo bere n’Ile-Ife nipinle Osun.
O ni, Tosde, ojo kerindinlogbon osu yii ni eto isin ale
onigbagbo yoo waye nile Oloogbe ni Alubata
Street, Alapata, Modakeke, ipinle Osun.
Fraide ojo keji ni won yoo seto isinku ni SS Peter and Paul
Catholic Church, Lagere Ile-Ife, nigba ti won yoo sinku oku si iteku SS Peter
and Paul Cemetery, n’Ile-Ife.
Iweje-wemu fawon alejo yoo tele e ni kete ti won ba ti sin
oku tan ni Seventh Day Adventist Pry School, nidojuko Seventh day hospital, Ibadan road, Ile-Ife, ipinle Osun.
Gbajumo oniroyin yii ti sapejuwe baba re gege ni ololufee
Olorun to fi gbogbo ojo aye re tele Kristi. Bakan naa lo so pe, “Baba daadaa to
gbiyanju lati toju awa omo debi to lapeere ni, ki Olorun ba wa te won safefe
rere, bee la o ri i daju pe a salekun awon ise rere ti won fi sile saye.”
Lara awon to gbeyin baba naa ni omo, omo-omo ati opolopo ebi
oun ara.
0 Comments