GBAJUMO

ILEESE YEFADOT ATI IJOBA EKO FE SETO AMAYEDERUN F'ARAALU

...BEE LANFAANI IPATE ITA GBANGBA YOO TUN WAYE

Lati le mu igbe aye irorun ba awon araalu, ileeese  YEFADOT National Mobile Market pelu ajosepo ileese Lagos state Ministry of Commerce and industry, iyen ileese to n ri si okoowo ati idase-sile ti setan lati seto ipate ita gbangba olojo merin niluu Eko.
Aare Ileese YEFADOT, Oloye Yetunde Babajide
Ninu atejade ti Aare ileese YEFADOT, Oloye Arabinrin Yetunde Babajide fi sowo si Magasinni yii  lo ti so pe,”Akori eto ti a fe se lodun yii ni a pe akole e ni AGBE L’OBA ati riro araalu ilu lagabra nipase sise eto ipate ita gbangba. Ohun ti a si fi se koko eto ohun ni lilo ise agbe lati fi ro araalu lagbara. 

O je ohun pataki fun wa lorile-ede yii loni-in lati mu ise agbe ni okunkundun. Ti a ba wo awon ise takuntakun ti awon asaaju orile-ede yii nigba kan, paaapaa lapa Iwo-oorun tiwa nibi, iyen awon ile Yoruba, a o ri i pe ise takuntakun lawon eeyan bi Oloye Obafemi Awolowo se, awon ohun meremere tijoba won si se lasiko naa si wa kaakiri ti a n foju ri bayii. 

Ona kan pataki tijoba West si fi ri owo se awon nnkan ribiribi ohun ni ise agbe ti awon baba wa laye igban naa koju mo gidigidi.”

O te siwaju ninu oro e pe, “Lara ohun pataki to maa waye nibi ipate ita gbangba ohun ni kiko awon eeyan lorisirisi ise owo, bee laaye tun wa fawon eeyan lati wa se kata-kara pelu fun odidi ojo merin gbako ti eto pataki yii yoo fi waye.
“Gbongan nla Adeyemi Bero ni Alausa Secretariat n’Ikeja l’Ekoo leto ohun yoo ti waye bere lati ojo ketadinlogbon (27th) osu yii titi di ogbonjo (3oth July). Aago mesan-an aaro ni gbongan ohun yoo ti wa ni sisi fun orisirisi ohun ti yoo maa waye nibe titi di aago mefa irole.

“Lara awon ohun ti won yoo se idanilekoo e fawon eeyan niwonyi: Tie & Dye; Bridal hand fan; purse and bag making, bi a se n se oda ti won fi n kun ile, ise aranso ati orisirisi idanilekoo nipa ise agbe lolokan-o-jokan pelu awon ohun mi-in to le mu ise kuro ninu aye omo eniyan.”

Ogunna gbongbo omo egbe oselu APC yii to tun je asaaju awon obinrin ninu egbe naa nile Yoruba so pe, “Lajori eto ta a fe se yii ni lati le ise lugbe. Niru asiko ta a wa yii, o se pataki ki a pada sidii ise awon baba nla wa, a gbodo wa ona ti ise; ebi ati iyan yoo fi dopin lorile-ede yii. Bakan naa la setan lati wa ona ti mekunnu naa yoo fi maa rowo na, ti igbe aye irorun yoo le wa fun kaluku.”
Siwaju si i, o so pe, “Ona ti yoo gba ro awon eeyan lorun la fi gbe eto ohun kale. Awon ti won je omo egbe wa yoo san egberun marun-un naira (N5000) fun iforuko-sile ati pipate oja won, nigba ti awon ti ki i se omo egbe yoo san egberun meje naira (N7000), iyen awon ti won ba fe pate oja.

“Awon ti won je Caterers (iyen awon olounje); Fashion designer (Telo); Palm-wine tappers (Awon ademu) yoo san egberun mewaa naira (N10,000), nigba ti awon ti won ba fe ta electronics, iyen awon ohun oso ile lorisirisi yoo san egberun lona ogun naira (N20,000).

Fun awon ti won ba fe kopa ninu eto soludero yii, won le kan si wa lori ero ayelujara yii: YEFADOT FOODSTUFFS TRADEFAIR tabi YEFADOT FOODSTUFFS, bakan naa lanfaani wa lati le pe awon nonba wonyi:  08035384150; 07082299696 tabi 08034067634



Post a Comment

0 Comments