![]() |
Mistura Aderounmu |
Tosde ojo keji osu kejo odun
yii ni gbajumo olorin esin Islam nni, Alhaja Mistura Aderoumu-Asafa yoo sayeye
ojoobi e l’Ekoo.
Ninu atejade to fi sowo si
Magasinni yii lo ti fidi e mule wi pe, oun fe sayeye naa lati fi dupe lowo
Olorun lori ohun rere gbogbo to n sele ninu aye oun. Aago kan osan lo so pe eto
ohun yoo bere ni 5 Essien Close, Chairman Street, Erunwen Ikorodu, l’Ekoo.
Laipe yii ni gbajumo olorin
esin Islam yii ba Magasinni yii soro lori rekoodu tuntun to fe gbe jade to pe
akole e ni Adun Igbeyawo. Akori orin
meta lo so pe o wa ninu rekoodu ohun; Adun Igbeyawo, Tuntun ati Asikiri, iyen
iranti Olorun.
Te o ba gbagbe, lodun 2003 ni Mistura
Aderounmu, eni tawon eeyan mo si Temi Ni Success ti ko ju omo odun mewaa-le-die
nigba yen gbe rekoodu nla kan jade, to pe akole e ni Temi Ni Success. Ni kete ti
rekoodu jade lo di nnkan ti awon eeyan n gbo kaakiri, bi Mistura omo kekere
jojolo nigba naa lohun-un se di gbajumo nla niyen titi di oni.
Leyin rekoodu Temi Ni Success
yii lo tun se awon wonyi; O dun lodun 2005; Ope mi lodun 2010; Gbigba Adura lodun
2014; ati eyi tuntun to fe gbe jade yii to pe ni Adun Igbeyawo.
Ninu oro to ba Magasinni yii so
lo ti so pe, “Mo dupe fun Olorun lori ibi to mu mi de loni-in, aleekun oore ni
mo n toro. Rekoodu tuntun ti mo se ni yoo je eleekefa ti mo se, bo tile je
opolopo ni mo ti se pelu awon akegbe mi atawon to ju mi lo nidii ise orin.”
Mistura Aderounmu te siwaju pe,
bo tile je pe orisirisi loju ti ri nidii ise ohun, paapaa bi oun se kere pupo
nigba yen, eyi to mu baba oun di manija oun, ki itosona to ye le wa fun oun. O
ni, “A dupe lowo Olorun wi pe gbogbo laala igba naa ko ja si asan, nidii ise
orin yii, a ti lo si Mecca, a n lo moto, bee ni Olorun tun ko ile ayo fun mi
pelu, ti Olorun si tun jogun oko alalubarika fun mi. Mo dupe o, ope mi ko lopin
rara.”
Ninu alaye ti gbajumo olorin
Islam yii se naa lo ti fidi e mule pe lara awon eeyan nla ti oun ko le gbagbe
ni Alhaji Wasiu Kayode Sidiq ati iyawo e, Alhaja Hafsat Sideeq, toun naa je
gbajumo olorin. O ni, “Latijo ti Alhaji Wasiu Sideeq ti koko foju kan mi ni won
ti nigbagbo ninu mi, bee ni iyawo won naa. Rekoodu akoko to so mi dolokiki,
iyen Temi Ni Success, Alhaji Kayode Sideeq lo ko owo ta a fi se sile, bo tile
je pe Afeezco pada da owo ohun pada fun won.
Lori rekoodu tuntun to n sise
lori e lowo, Mistura ti so pe, “Ile oko lemi naa wa, bee ni mo mo adun
igbeyawo, idi niyen ti mo fi gbe rekoodu jade lati salaye bi o ti se dun to,
atawon ohun ti eeyan le ba pade, sugbon koko ibe ju ni pe, suuru ati igbagbo
sinsin ninu Olorun leeyan le fi ri adun igbeyawo.”

Siwaju si i, o ti so pe ona kan
ti eeyan le gba fi lokiki nidii ise orin ni ki eeyan bowo fun awon ti won wa
niwaju, ki eeyan sim aa wo aago alaago sise, nitori o ni igba ati akoko ti
Olorun ti ko fun kaluku.
0 Comments