...WON NI EEDI FAYOSE LO MU UN
Nipinle Ekiti niluu Ado nisele ohun ti waye lasiko ti
won n se ipolongo ibo fun Dokita Kayode Fayemi to n dije dupo gomina labe asia
egbe oselu APC.
Orisirisi eeyan lo ti soro, nigba ti asiko si to fun
okunrin oloselu omo Ibo nni, Chris Ngige lati soro, nise lo pariwo to ni, eyin
ara Ekiti, n je e setan lati da a pada abi e ko fe e lojo Satide to n bo yii?
O
ni, Fayose ni ke e dibo yin fun oooo. Lasiko to n soro yii, nise lo fi oro
Fayose sapejuwe obinrin daadaa to wa nile alaya meji to mo itoju oko daadaa. O
ni, “Ti okunrin ba ni iyawo meji, ti okan n se daadaa, to fi oko lokan bale, to
mo itoju se, irufe iyawo bee gan-an ni Fayose n se.”
Lojuese ti gomina ipinle Anambra tele yii, to tun ti se seneto ri ko
too di minisita ninu ijoba Muhammed Buhari beere lohun rara wi pe se awon eeyan
Ekiti fe Fayose tabi won ko fe e, tawon yen si pariwo pe rara awon ko fe e mo,
asiko yen gan an lokunrin yii too mo pe dipo ki oun so pe Fayemi, ariwo Fayose
loun n pa.
Loju ese naa lo ti so pe oruko awon Ekiti ti jora ju,
Fayose, Fayemi, Falade, Falana ati bee bee lo. Nibe gan-an lawon eeyan kan ti n
so pe, o jo pe oro okunrin naa ki i se oju lasan, won ni eedi Fayose lo mu un.
Loju gbogbo awon omo egbe e gan-an lo se, Buhari, Tinubu, Kayose
Fayemi, Bisi Akande, Adams Oshiomhole to je alaga egbe won paapaa wa nikale.
E wo fidio to wa nisale yii
0 Comments