GBAJUMO

O ma se o! Omo igbakeji gomina ipinle Ondo ku sile okunrin

Ninu ibanuje nla ni idile igbakeji gomina tele nipinle Ondo, Labisi Oluboyo wa bayii lori iku ojiji to pa omo re, Adenike Oluboyo niluu Akure.

Nile orekunrin e, eni ti won pe oruko re ni Adeyemi Alao ni won ti ba oku omobinrin naa labe beedi.
Gege bi alaye ti alukoro ileese olopaa nipinle Ondo, Femi Joseph se fun ileese News Agency of Nigeria (NAN), nibi to ti fidi e mule wi pe loooto nisele ohun waye, ati pe nile orekunrin e gan-an ni won ti ba oku e laaaro oni, Sannde. Bakan naa lo fi kun un pe iwadii n lo lowo lori ohun to pa omobinrin naa ati pe laipe yii ni ileese olopaa yoo se orinkinniwin alaye lori bi isele ohun se waye.
Ninu iwadii naa ni won ti fidi e mule wi pe Princess Nikky lawon eeyan tun mo oloogbe ohun si.  Won ni leyin ojo die ti won ti n wa a ni won ba oku e nile orekunrin e niluu Akure, ipinle Ondo.

Akekoo Educational Management ni won pe e, ipele to keyin eko ohun ni won so pe o wa. Ohun tawon kan si n so ni pe oun ati orekunrin e, Adeyemi Alao eni tawon eeyan tun mo si Q.S ninu ogba ileewe naa ni won jo ri papo ko too dawati. 



Post a Comment

0 Comments