![]() |
Kayode Fayemi, gomina tuntun ti won dibo yan l'Ekiti |
Bakan naa lo ti fi da gbogbo awon eeyan ipinle Ekiti loju lasiko to n ba awon oniroyin soro wi pe o ti di dandan ki oun sewadii ijoba Fayose, ni kete ti oun ba ti depo ase.
Fayemi te siwaju ninu oro e pe, “Bi eni pala senu lo maa je ti mo ba so pe mi o ni tu idi ijoba Fayose wo, o ti di dandan ki a ye ohun ti won ti gbe se nipinle Ekiti lati nnkan bi odun merin seyin ti won ti wa nipo ijoba wo.”
Te o ba gbagbe, okunrin oloselu omo egbe APC yii lo jawe olubori ninu ibo to waye lana-an Satide, ojo Abameta, ojo kerinla osu keje odun yii. Ibo to fe to egberun lona igba (197, 459) lo gbe Kayode Fayemi wole, nigba ti Ojogbon Kolapo Olusola to dije loruko egbe oselu PDP ni ibo to fe to egberun lona ogosan-an (178,121).
Bi awon omo egbe oselu APC se n jo, ti won n yo kaakiri, awon omo egbe oselu PDP naa ti soro, ohun ti won si so ni pe, awon ko fara mo esi ibo ohun, ati pe awon kudie-kudie kookan wa ninu esi ibo ti won so pe o gbe Kayode Fayemi wole.
![]() |
Fayose niyi, (Oshokomole) gomina ti yoo pari ise laipe |
Sa o, Dokita Kayode Fayemi naa ti soro, o ni anfaani wa fun egbe oselu PDP lati gba ile ejo Tribunal lo, o ni, eto idibo wa ni Nigeria faaye sile fun un.
Bakan naa lo so pe, oun setan lati sise papo pelu Gomina Fayose niwon igba die to ku to maa lo lori aleefa yii ki owo osu awon osise ti gomina naa je sile le je sisan ki oun too bo sori aleefa.
Bee lo tun fi da awon eeyan ipinle ohun loju pe, owo osu won loun yoo sare mu ni okunkundun, nitori ti won ba ri owo osu won gba deede naa ni eto oro aje ipinle ohun yoo le ru gogo, ti ara yoo tu olori ati elemu.
Ju gbogbo e lo, Dokita Kayode Fayemi ti so pe, ko si bi Fayose se fe se e ti ijoba oun ko nii ye idi okunrin naa wo, o ni, “O ti di dandan ki a topinpin bi won se sejoba ipinle Ekiti fun podun merin.
Asiko otun lo de yii, ohun gbogbo pata lo si gbodo wa lotun-lotun, asiko yii gan-an lawon eeyan ipinle Ekiti yoo ri ayipada nla nitori ifaseyin gidi ni ijoba Fayose mu ba ipinle Ekiti, ilosiwaju aseyori gan-an lo wole de yii.”
0 Comments