GBAJUMO

OPONU EEYAN NIKAN LO LE SO PE EMI NI MO RAN AWON ADIGUNJALE NISE L'OFA - GOMINA KWARA

Gomina ipinle Kwara Abdul-Fatah Ahmed ti bu enu ate lu awon eeyan kan ti won n gbe e kiri wi pe owo oun ati Aare ile-igbimo asofin, Bukola Saraki ko mo ninu idigunjale to waye l’Ofa, nipinle Kwara ni nnkan bi osu meloo kan seyin.

Ninu iforowero ti won se fun gomina yii lori ero
amohumaworan nni, Channels Television lo ti fidi e mule wi pe, “O je ohun ti o seni ni kayeefi, to si pani lerin-in, bi awon eeyan kan ba le maa so pe emi ati Dokita Bukola Saraki lowo ninu irufe iwa ti ko le mu idagbasoke ba ilu, paapaa ilu Ofa to je pe orisirisi eto to le mu ilu gbooro si i, ti yoo si mu aye irorun ba araalu nijoba wa ti se sibe.”

Gomina ipinle Kwara so pe ko see se ki oun tabi okunrin asaaju oloselu ni Kwara, Bukola Saraki lowo ninu bi awon janduku kan se kogun ja awon banki, ti won tun pa eeyan repete pelu awon eso agbofinro ti won yabo ni tesan won niluu Ofa.

Te o ba gbagbe, ojo karun-un osu kerin odun yii lawon janduku kan kogun ja awon banki kan niluu Ofa nijoba ibile Ofa nipinle Kwara. Eeyan bii ogbon ni won pa danu ninu isele ohun, bi alaboyun se wa ninu won, bee lomode ati agbalagba, bakan naa lawon olopaa naa ku ninu isele ohun leyin tawon janduku kolu tesan won.

Ni kete tawon kan ti n gbe e kiri wi pe gomina ipinle ohun, Abdul-Fatah Ahmed mo nipa isele ohun, nitori ti ninu awon janduku ohun so pe awon maa n sise fawon oloselu ni Kwara ni gomina naa ti ke gbajare wi pe, ko si ooto kankan ninu oro ohun, bee ni Seneto Bukola Saraki naa ti so pe, ibaje eeyan lasan ni o, oun ko ran won nise iru e rara.


Post a Comment

0 Comments