GBAJUMO

Oselu etanu ni won fe fi koba mi - Bukola Saraki pariwo

Tilu-tifon lawon eeyan gba igboro kan niluu Ilorin nipinle Kwara lasiko ti iroyin gbode wi pe Dokita Bukola Saraki, aare ile igbimo asofin ti bo lowo ejo ti ijoba apapo n ba a fa.
 
Kaakiri ilu Ilorin lawon omo egbe oselu okunrin yii, paapaa awon ololufe e n jo kiri, ti won si n pariwo ‘Sai Bukola’ lati ba a dawo idunnu.

Laipe yii ni igbimo eleni marun-un tile-ejo to ga ju, iyen Supreme Court, ti Adajo agba, Centus Nweze dari kede pe Bukola Saraki ko ni ejo kankan lati je lori esun ti won fi kan an lori dukia to kede pe oun ni, sugbon ti won ni ko so ododo lori e.

Ni kete ti iroyin ohun gbalu lawon  eeyan Kwara, paapaa niluu Ilorin ti gbalu repete, ti won n jo, ti won n yo, bee gege ni gomina ipinle ohun, Abdul-fatah Ahmed naa ko sai fi idunnu han, paapaa.

Lojuese ti idajo ohun waye ni Seneto Bukola Saraki naa ti soro, ohun to si so ni pe, “Mo dupe lowo Olorun to fidi ooto mule. Ojo kejilelogun osu kesan-an odun 2015 ni ejo yii bere, bi ojo meji-din-legbefa (1018) ni won fi ba mi sejo ohun.”

“O je ohun iyalenu fun mi nigba ti won pe mi lejo lori dukia ti mo ti kede wi pe mo ni lati nnkan bi odun meedogun seyin, ti won sese wa pe mi lejo lori e lodun 2015. Mo mo daju nigba yen wi pe isubu mi ni won fe fi ejo ohun wa, ati pe oselu etanu ponbele ni won n se dipo ki a jo fowosowopo lati jo sise ilosiwaju fun orile-ede yii.”

Seneto Bukola Saraki ti wa dupe lowo awon akegbe e, bee lo tun dupe lowo eka idajo orile-ede yii lori igbejo ododo naa.

Post a Comment

0 Comments