GBAJUMO

PASITO CHRIS OKOTIE FE DIJE DUPO AARE LABE ASIA EGBE PDP ATI APC

Ninu soosi e, iyen Household of God lasiko ti isin n lo lowo laipe yii ni Oludari ijo naa, Christopher Okotie kede fawon omo ijo e wi pe, oun tun ti gbo ohun Oluwa, ati pe o ti di dandan bayii ki oun tun jade dupo aare leekan si i.
Pasito Chris Okotie ree lasiko to n ba awon omo ijo e soro
Bi awon egbe oselu lorisirisi lorile-ede yii se n mura fun ibo gbogboo-gbo ti yoo waye lodun to n bo yii, okunrin ojise Olorun yii ti so pe ki awon egbe oselu mejeeji, iyen APC ati PDP ti won je oguna gbongbo lorile-ede yii ma wule yo ara won lenu lati fa enikeni kale mo bikose oun.

O ni, “Mo ti ko leta ranse si egbe oselu mejeeji PDP ati APC, ohun ti mo si ko sinu e ni pe, ki won ma wule da ara won laamu lati fa enikeni sile lati dije dupo Aare. Mo setan lati je oludije fun egbe mejeeji. Mo fe ki egbe oselu APC ati PDP pawopo mu mi gege bi oludije won.”

Pasito Okotie fi kun oro e pe, “Nnkan ko rogbo lasiko ti a wa yii, o si se pataki ki a tete wa ojuutu si i ki nnkan too baje ju bayii lo.”
Lodun 2003 ni gbajumo olorin taka-sufee yii, ki o too di ojise Olorun koko gbe apoti ibo Aare orile-ede Nigeria, bee gege lo tun jade lodun 2007 ati odun 2011, sugbon bi ere osupa loro ohun se ri nigba meteeta oto to jade, nitori ko si aseyori kan bayii to ri se lasiko ibo ohun.

Ni bayii, Pasito Okotie loun ti pada sidii oselu, nitori pe asiko yii gan-an lawon omo Nigeria nilo eniyan bii oun. O ni, oun kunju osunwon, bee loun tun to tan lati tuko orile-ede yii debute ogo. Bakan naa lo so pe iwe ofin ti a n lo lorile-ede yii ko ba igba mu mo, ati pe atunse ati atunto gidi gbodo waye lori e ki ojo ola Nigeria baa le dara.
Asia egbe oselu mejeeji to ko leta si

Siwaju si i, o ni isoro to n koju orile-ede yii koja oro oselu nikan, ati pe ko si eyikeyi ninu egbe oselu APC tabi PDP to le tan isoro Nigeria lasiko yii. O ni, “Ni bayii, mo ti setan lati tun dije du ipo Aare. Lasiko yii, irufe eni ti Nigeria nilo nipo apase ni oloooto eeyan, eni to ni iberu Olorun; to setan lati mu isokan orile-ede yii ni okunkundun, ti yoo duro nidii ooto, ti yoo le satunto ati atunse si oro Nigeria. Ologbon, onilaakaye, ti yoo fi ife ati iberu Olorun satunto ilu, iru eeyan yii gan-an ni Olorun fun mi ni oore lati je, bee mo setan lati mu igbe aye irorun ba ati olori oun elemu.  Ijoba tiwa yoo wa ojuutu si atunto ati atunse Nigeria ni kete ti mo ba ti dori ipo.”

Chris Okotie ti so pe, erongba oun ni lati sagbekale ijoba fidi-hee ti yoo wa ojutuu si atunto ati atunse si oro Nigeria, eyi ti yoo fun wa ni anfaani igba otun lorile-ede yii.


Post a Comment

0 Comments