GBAJUMO

RONKE OSODI OKE ATI LIZZY ANJORIN TUN PADE LODE ARIYA

...NI WAHALA MI-IN BA TUN BE SILE LAARIN WON

Gbajumo osere tiata kan ti oruko e n je Kemi Korede lo dana ariya repete l’Ekoo, nibe gan-an ni Arabinrin Ronke Ojo, eni tawon eeyan tun mo si Osodi Oke ati Lizzy Anjorin tun ti rinna pade, nni wahala mi-in ba tun so laarin awon osere tiata yii.
Ronke Ojo Anthony
Se o fe ma si eni ti ko mo lawujo awon osere wi pe ija buruku n lo laarin Ronke Ojo aya Anthony ati gbajumo osere tiata nni, Alhaja Aisha Liz Anjorin.

Ni nnkan bi ose meloo kan seyin ni ija ohun bere, fidio kan ni Ronke Osodi Oke ju sigboro. Ninu e lo ti bu enu ate lu bi awon osere lokunrin ati lobinrin se maa n polongo aseyori won lori ero ayelujara, iyen social media.

Osodi Oke ni ki i se ohun to bojumu bi awon osere se maa n sare lo sori ero ayelujara lati kede wi pe awon sese ra moto, tabi awon kole atawon aseyori mi-in. Obinrin yii fi kun un pe ti isu eni ba ta, nise lo ye ki eeyan rora dawo bo o je.
Lizzy Anjorin

Ohun to ju sigboro ree, ki oloju si too se e, Lizy Anjorin ti fun un lesi, o ni oun lobinrin naa n ba wi, ati pe bi oun se maa n gbe orisirisi nnkan sori ero ayelujara lo n bi Ronke ninu ki o too so o sita bayii. Lizy ni, oun fi n dupe lowo Olorun ni, paapaa iya oun to wa lode orun. 

O ni, “Kani oju oku ba n to eyin ni, nise ni inu iya mi a maa dun lori aseyori mi. Emi ko gbe awon aseyori mi sori ategun lati fi ba enikeni ninu je, sugbon ohun ti Osodi Oke so yen, emi lo n ba a wi, bee emi ko gbese ran an rara, ati pe ara lo n ta a, nitori pe baara lo maa n gba loju agbo lasiko ti won ba pe e fun atokun eto, iyen MC. Emi o ni ki enikeni ma saseyori, onisowo ni mi, o si di dandan ki n polowo awon oja mi lori ero ayelujara, ti Ronke ba wa ri iyen gege bi faari, oun lo mo yen o.”

Nibi ti wahala won ti bere niyen o, nigba ti won si tun pade ni Sannde to koja nibi ti Osodi Oke ti n se MC, iyen adari eto, ti obinrin yii n so pe oun ko le ma toro owo, lojuese ni Lizy tun ti gba ori Instagram lo, to si tun so pe oun lo n ba wi, ati pe obinrin naa ko sebi eni kunju osunwo to nidii ise, ati pe anfaani wi pe owo e ni ero agbagbe wa lo se raaye maa foro gun oun lara. Obinrin yii ni kani oun ko ba se e laakaye ni, iwa ti Osodi Oke hu lojo naa le mu awon da ode ariya naa ru, iyen ti oun ba fi ibinu oun han nibe.

Bi oro ohun ti se n gbale kiri, bee ni Ronke naa ti fesi, iyen lasiko to n mura ojoobi to se loni-in. Bi awon eeyan se n ki i ku oriire, ti inu oun naa si n dun, sibe gbajumo osere tiata yii ko sai ju fidio kan sigboro, eyi tawon eeyan n wo kiri bayii.
Ronke Osodi oke ree 

Lasiko to n palemo ayeye ohun, nibi to ti lo ya orisirisi foto to fe fi sami ojoobi e lo ju fidio kan sigboro, ohun to si so ninu e ni pe, oun ko ni i ye maa toro owo loju agbo ni toun, paapaa nibi ti won ba ti n se ifilole sinima, nitori pe oun ko leni akoko to maa koko se bee laarin awon to maa n dari eto, iyen awon MC lokunrin ati lobinrin.

O ni, “Emi ko leni akoko to maa maa toro owo loju agbo, bee ki i se gbogbo ode lemi ti maa n toro owo, afi eyi ti won ba n se ikowojo, nibe nikan ni mo le ti soro aje sapo ara temi naa. Inu mi dun wi pe mi o toro owo lowo eni to n bu mi kiri yii, bee ni mi o ya aso lowo e ri, bo tile je pe mi o laso to o, sugbon mo dupe lowo Olorun lori ohun gbogbo to se fun mi.”

Gbajumo onitiata yii ti fi da awon ololufe e loju wi pe, leyin fidio ti oun gbe sita lasiko ojoobi oun yii, oun ko tun ni so ohunkohun mo lori oro ohun. O ni, “Ti o ba wu obinrin ti mo n so yii ko bu mi, tabi fo mi leti, pinrin bayii mi o ni i so lori oro yii mo, nitori oro ija ko lo n se mi.”

Sa o, Lizy Anjorin naa ti se fidio tie naa o, bo tile je nise lo koko ki Ronke Osodi Oke ku ojoobi e, to si sadura fun un pe lodun to n bo, nnkan yoo ti se jomu-jomu fun obinrin naa ju bayii lo
Yato si adura to se yii, Alhaja Aisha, iyen Lizy Anjorin ko sai ko oro kan sabe awon fidio kan to ju sori afefe, nibi to ti n na Kemi Korede oninawo ati Pasuma lowo loju agbo. Ninu oro e lo ti fehonu e han lori ihuwasi Ronke Osodi Oke loju agbo lojo naa. 

O ni, obinrin naa ko huwa bii eni to kosemose rara, nitori ohun ti ofin ati ilana ise sinima la kale ni pe ti ise ba pa iwo ati eni te e jo nija papo, ikunsinu yoowu ti e ba ni pelu ara yin, e gbodo gbe e ti, ti e ba pari lori itage, e le bere ija yin pada.
Alhaja Aisha Lizy Anjorin

Obinrin onitiata yii so pe, gbogbo owe ti Ronke Osodi n pa mo oun loun gbo, sugbon ori lo yo o wi pe oun ko gun ori itage wa ba a, ati pe ti o ba tun seru e foun lojo mi-in, o see ki oun fi ero agbegbe to mu dani da seria fun un.

Osere tiata kan ti Magasinni yii ba soro ti so pe, “Wahala to wa laarin awon osere tiata mejeeji yii, afi ki awon ti won je asiwaju wa tete ba won yanju e, arikose ni won je fun opo laarin ilu, bi won se n pe ara won loruko, ti won n yeye ara won kiri yii ko bojumu rara.”

Post a Comment

0 Comments