GBAJUMO

RUKAYAT GAWAT OLORIN ISLAM PATE IDIJE FAWON MUSULUMI L'EKOO

Alh. Rukayat Gawat.
Lati sagbelaruge imo Qur'an laarin awon omode atawon agbalagba ti won je Musulumi, gbajumo olorin Islam nni, Alhaja Rukayat Gawat Oyefeso ti gbe idije kika ayoka ninu Quran ati idije imo nipa Islam kale l'Ekoo.
Ninu alaye e lo ti so pe, "Ipele meji otooto ni idije kike ayoka ninu Quran pin sin, ipele akoko wa fun awon omode ti ojo ori won ko ju odun mejo si mewaa lo, nigba ti awon to wa nipele keji je omo odun mokanla si mejindlogun.
Yato si eyi, idije imo nipa Al'Quran naa yoo waye laarin awon olukopa ti won ti balaga lokunrin ati lobinrin.
Ruka Gawat, eni tawon eeyan tun mo si Sheikha ati Queen of Music salaye pe, " Gege bi olorin Islam, ohun to je egbe akorin mi logun ni ona lati tubo kede esin asinla yii faraye, yato si pe a n forin se waasi fun omode ati agba. Imo nipa Al'Quran je ohun pataki fun gbogbo musulumi nitori pe gbogbo ohun ti eeyan nilo lati mo nipa aye yii lo wa ninu e, bee gege lohun ti a o ba pade, ta o ba si laye mo ni Quran salaye lekunrere. Fun idi eyi, bi a se sagbekale eto yii fawon omode, bee lo wa fun awon agbalagba pelu, bee lebun si wa fun awon olukopa lati je lorisirisi. Lajori e naa ni lati fi se koriya fawon omo wa ti won le ka Kuraani daadaa atawon ti won ni imo nipa esin Islam pelu. Se ohun tawon Afaa wa so fun wa ni pe imo lo ni adinni, ogbon ori ko gbe e."
Ojo keedogbon osu yii ni eto ohun yoo waye ni Ansarudeen Mosque ni nomba 25 Coker street mushin, l'Ekoo.
Okan Lara awon olorin esin Islam to gbajumo daadaa ni Rukayat Gawat aya Oyefeso n se.
Opolopo rekoodu lo ti gbe jade, eyi to so o di ilumooka olorin nla. Bee gege lo ti gba awoodu lorisirisi fun aseyori awon ise to ti lojuna orin esin Islam.

Post a Comment

0 Comments