GBAJUMO

TILU TIFON NI WON FI SIN RONKE PHOTO L’OYOO


Bi omi lawon eeyan ti n ya wo ilu Oyo lati Tosde, ojo kokanla osu yii fun ayeye isinku Oloye Felicia Oyeronke Sangogbenle, nigba ti yoo si fi dojo keji, Fraide, nise ni ilu Oyo gan-an mo pe oun gba awon alejo lorisirisi.
Ojo keedogun osu karun-un odun yii ni Oloye gbajumo onifoto, iyen ayaworan, eni to tun je onisowo pataki niluu Oyo jade laye. Oke okun ni iku ka obinrin naa mo lasiko to lo fun ara nisinmi lodo okan lara awon omo e.
 Ojo kerindinlogbon (26) osu kewaa odun 1950 ni won bi i niluu Fiditi, nipinle Oyo, leyin to lo odun metadinlaaadorin (67), iyen ojo keedogun osu karun-un odun 2018 yii lo dagbere faye.

Odun 1970 ni Felicia da duro leyin to kose foto tan, ko si pe ti won fi mo on gege bi gbajumo nla nidi ise ohun, ti won eeyan si n pe e ni Ronke Photo ni adugbo kan to n je Owode nigboro Oyo nibi ti studio re wa.
Awon omo ti Felicia ko nise foto tawon naa ti n se daadaa nidi ise ohun fee to aadorin, kaakiri agbaye ni won si ti n sise foto ohun bayii.

Ni kete ti won gbe oku arabinrin yii de ni eto isinku e ti bere. Ilu abinibi e ni Fiditi ni won koko te e si, ki won too se isin ale onigbagbo fun un nile e ni Odo-Eran niluu Oyo.
Aago mokanla owuro ko ti i lu ti First Baptist Church to wa ni Oke Isokun l’Oyoo ti kun foofo, bi awon omo olokuu si ti wole ni eto isin ti bere. Bi inu soosi se kun, bee lawon eeyan to wa nita paapaa ko lonka, gbogbo won pata ni won wa seye ikeyin fun Mama Tunde. Leyin waasu ati isin lorisirisi loruko oku naa ni won gbe e lo sile e l’Odo-Eran, nibe gan-an ni won sin Ronke Photo si, tawon omo si ko awon eeyan to wa seye ikeyin fun mama won lo si papa isere Olivet Baptist High School niluu Oyo.

Lara awon to gbeyin Oloye Ronke ni Alagba John Sangogbenle, eni ti se oko oloogbe bee lawon omo bii; Tunde Sangogbenle, Bosede Ojo, Tayo, Sola, Nike, Busayo ati opolopo oko omo, aya omo atawon omo omo.
Ninu oro Tunde Gbenle lo ti sapejuwe mama re yii gege bi abiyamo nla to sike omo doju ami. O ni, “Lojo ti mo gbe won lo si papako ofurufu Muritala Muhammed l’Ekoo, mi o mo pe igba keyin ti a o rira laaye niyen, mama dagbere fun mi, sugbon mi o mo pe idagbere ikeyin niyen. A fe e loooto sugbon Olorun to da a, to ni in fe e ju gbogbo wa, lagbara Olorun ise to fi sile ko nii yi danu.”

Lara awon eeyan pataki to wa nibi ayeye isinku ohun ni omo ile igbimo asofin agba, Onarebu Hakeem Adeyemi, eni ti se omo Alaafin Oyo. Bakan naa lawon asoju Oba Lamidi Adeyemi naa wa nibe pelu atawon alejo pataki mi-in kaakiri ile Yoruba atawon ibomi-in ti Ronke Photo ti soro aje lo.  


Post a Comment

0 Comments