![]() |
Posita tawon eeyan n gbe kiri ree Gbemisola ati Buhari le n wo yen |
Bi
posita yii se wa lawon ibi kan n’Ilorin, bee gege lo ti wa lori ero ayelujara,
ti awon eeyan n pin in kiri. Ohun to wa mu opo eeyan maa wo o wi pe oro oselu
ohun yoo gbona janjan ni pe, ekun idibo, iyen (Kwara Central) ti Bukola Saraki
n soju fun niluu Abuja nile igbimo asofin agba, ekun idibo yen gan-an ni
Gbemisola naa fe dije fun lodun 2019.
Te
o ba gbagbe, igba akoko ko niyi ti awon Saraki mejeeji yii yoo koju ija sira
won lori oro oselu, paapaa lasiko ti baba won wa laye.
Se
ni nnkan bi odun mejo seyin loro ohun waye, Bukola Saraki ni gomina ipinle
Kwara nigba yen. Bo ti se n palemo lati kuro nile ijoba lo ti ni in lokan lati fi
komisanna re sipo ohun, iyen Abdul-Fatah Ahmed. Oloye Olusola Saraki ko faramo
igbese ohun nigba yen, omo e obinrin, Gbemisola lo wu u lati lo, iyen gan-an lo
si mu won da egbe okere sile ni Kwara, ti Bukola Saraki si di egbe oselu PDP mu
sinsin nigba yen.
Loooto
ni ibo ohun gbona janjan lodun naa lohun-un nitori fa-a-ka-ja ohun laaarin Baba
Oloye, iyen Olusola Saraki ati omo e, Bukola Saraki ni. Nigbeyin, Saraki kekere
lo jawe olubori, ti baba e, to je asaaju oloselu ni Kwara ati aburo e Gbemisola
si fidi remi. Bi Fatai Ahmed, komisanna fun eto isuna owo ninu ijoba Bukola se
di gomina Kwara niyen.
![]() |
Awon omo egbe oselu APC ni yii, awon ni won so pe ki Saraki kowe fipo sile n'Ilorin |
Ni
bayii, ti wahala ti wa ninu egbe oselu APC tawon eeyan n ya kuro ninu egbe ohun
lojoojumo, irufe darudapo yii naa ti n sele lowo ni Kwara. Ninu iwode kan to
waye loni-in lawon omo egbe oselu APC ti won lawon n se ti Muhammed Buhari ti
sewode loni-in. Ohun ti won si so ni pe, ki Aare ile igbimo asofin, Seneto
Bukola Saraki kowe fi ipo e sile, nitori pe awon ko ri i bi omo egbe naa mo. Won
ni, nise lo kan n gbeyin ba ebo je fun egbe oselu APC.
Bi
iwode tiwon se n lo lowo, bee lawon mi-in naa kora jo ti won lo sile ijoba lati
lo fi ife ati idurosinsin won han fun gomina ipinle naa. Nibe gan-an ni Gomina
Abdul-Fatah Ahmed ti ba won soro, to si so pe, inira ni egbe oselu APC n koba
awon, ati pe laipe yii lawon yoo digba-dagbon kuro ninu egbe ohun lo sinu egbe
oselu mi-in ni kete tawon ba ti gbase lati oke.
Sa
o, bi awon kan se n jo, bee ni won n yo nile ijoba, ti won si mu kaadi egbe
oselu PDP dani yeyeye.
![]() |
Gomina Fatai lasiko to n ba awon omo egbe soro |
Ohun
kan ti awon eeyan si n so ni pe, odun 2019 yoo tun gbona janjan leekan si i nile
awon Saraki pelu bi awon oloselu se fe mu Gbemisola ati Booda e, Bukola Saraki
koju ara won leekan si i.
0 Comments