GBAJUMO

ALFA MI NI OLORIN ISLAM LO SI MECCA *O NI, KAWON OMO NIGERIA GBADURA GIDIGIDI

Alfa Mi ni ree ni Mecca

Bi awon Musulumi kan se wa lorile-ede Saudi-Arabia lati sise hajj odun yii, okan lara awon olorin esin Islam, Sheik Ismail Aderemi toun naa wa lohun-un ti ke si awon omo Nigeria lati lo akoko yii fi wa ojuure Olorun.
Gbajumo olorin esin Islam yii, eni tawon eeyan tun mo si Alfa mi ti so pe ohun pataki ti o gbe oun lo si orile-ede Saudi fun ise hajj odun yii ni lati be Olorun fun aanu re lori orile ede wa Nigeria. Bakan naa lo so pe oun yoo lo akoko ohun lati fi toro ike ati ige fun gbogbo awon ololufe oun pata.
Sheik Aderemi ti wa  ro gbogbo Muslumi pata lati lo asiko yii fi wa ojuure Olorun, ki orile-ede Nigeria le toro, paapaa bi eto idibo odun 2019 se n sunmo etile.
Alfa mi fi kun un pe, “Ohun idunnu lo je fun mi lati pelu awon Musulumi akegbe mi lati jo peju siluu Mecca lodun yii. Eko nla ni irin-ajo yii je, bee mo nigbagbo wi pe orile-ede Nigeria naa yoo dara. Ohun to se pataki fun wa gege bi olusin-Olorun ni ka toro aforiji ese wa, ki a si bebe fun aanu Olorun. Nibi ta a wa yii, aaye adura gbigba ni, mo si nigbagbo pe gbogbo ohun ti a ba Olorun so lori ilosiwaju orile-ede wa Nigeria ni yoo gbo, ti ayo ati idunnu yoo si bere si sele lorile-ede wa.”
Okan ninu awon olorin esin Islam to n se daadaa lorile-ede yii ni Sheik Ismail Aderemi eni tawon eeyan tun mo si Alfa mi. Bi gbajumo olorin esin Islam yii se je akorin, bee lo tun je Alfa nla, to si mo otun yato si osi ninu esin Islam. Rekoodu e akoko lo pe ni Alfa mi ni, Mo se Kidimo ni ikeji, bee lo tun ti se omi-in tawon eeyan si n gbo o daadaa. Ninu igbiyanju e naa lo ti mu roinn hip-hop mo orin ti o n ko, tawon ololufe e si n gbo o kaakiri.
Okan lara awon Musulumi ti won jo
pade lohun-un
Ninu awon iforowanilenuwo to se pelu Magasinni yii lo ti fidi e mule ohun to gbe e dedii ise orin, o ni, “Alfa ni mi, orile-ede Saudi Arabia ni mo ti kekoo ki n too pada si Nigeria, ohun ti mo le so pe o sun mi dedii orin ni awon aleebu kookan ti mo ri i pe o ti n sawo inu orin tawon elesin wa n ko. Ohun ti emi wa se ni lati satunse. Niwon igba ta a ti mo otun yato si osi, ojuse tiwa ni lati satinse ki esin Islam le tubo gbooro ju bayii lo.”
Alfa mi ni ti so pe ni kete ti Olorun ba ti so oun pada si Nigeria loun yoo bere ise lori rekoodu tuntun nipa iriri oun, bee ni yoo tun ni awon akanse adura tawon eeyan le maa gbo ati maa lo fun bibe Olorun.  

Post a Comment

0 Comments