GBAJUMO

ANKARA AYEYE BIOLA FAME DAKARA *WITIWITI NI WON N BO O


Orisirisi awon olorin esin atawon gbajumo akorin mi-in ni Efanjeliisi Biola Akala, eni tawon eeyan tun mo si Biola Fame ti setan bayii lati pe sibi ikojade rekoodu e tuntun to pe akole e ni Aanuoluwa.
Sannde, ojo kesan-an osu kejila odun yii lo so pe ayeye ohun yoo waye ni gbongan nla Hadassah Place 21, Emmanuel HIgh street, Ogudu  Ojota, l’Ekoo. Lara awon olorin ti yoo da awon eeyan laraya lojo naa ni, Lanre Teriba (Atorise), Dare Melody, Esther Igbekele, Bunmi Omije oju mi, Oba Ara, Seyi Lewis Alapanla, Rukayat Gawat, Biyi Samuel, Seyi Pleasure, Modinat Asabi Baritide; Bidemi Bright, Seyi Michael; Aduke Gold, Omotola Ohun Ayo; Ahmad Alawiye, Rukayat Basirimi, Sikiru Lemon; Mistura Aderohunmu; Addis Islamic Hip-Hop atawon gbajumo osere tiata lolokan-o-jokan.
Ninu oro e lo ti so pe, “Ifilole rekoodu tuntun ti mo fe se yii, ara oto ni yoo je. Se igba akoko ko niyi ti maa serufe ayeye yii. Oro mi dabii eni ti won ti ro pe ko le pago ni, sugbon ti Olorun alaaye loun setan lati kole alaruru fun. Nigba ti mo padanu iya mi to je alatileyin egbe akorin mi, nise ni mo sebi gbogbo e pata ti tan, sugbon pelu idurosinsin Olorun alaaye, mo setan lati gbona ara yo.”
Yato si ikojade rekoodu e tuntun to pe ni Aanuoluwa, awon nnkan mi-in to tun fe se lojo naa ni ifami-eye da awon eeyan lola, paapaa awon ti won gbarukuti egbe akorin e ni kete to ti bere lati nnkan bi ogun odun seyin.

                                                                           

Post a Comment

0 Comments