![]() |
Salvador |
Alaga fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Ọnarebu Moshood Salvador, ti ke si alaga ẹgbẹ oṣelu naa lapapọ niluu
Abuja lati le Oloye
Bọde George atawọn eeyan mẹwaa
mi-in kuro ninu ẹgbẹ naa bi wọn ba
fẹ jẹ koun ṣiṣẹ gẹgẹ bi ipo ti wọn yan oun si.
O sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsde, nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa ṣe ipade pọ,
eyi to waye laduugbo Maryland niluu Eko. O sọ pe ọkunrin
naa to n pe ara ẹ ni
olori ẹgbẹ naa
lo n da wahala silẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ohun, ati pe nise lo n fẹ kawọn
eeyan maa gbaṣẹ lẹnu rẹ ki wọn too ṣe ohunkohun, bee lo tun fe ki won maa se gbogbo eto egbe naa ninu
ile ẹ.
Bakan naa lo sọ pe bi ki i ba ṣe ọpẹlọpẹ Ọlọrun, o ku diẹ ki Bọde
George ran oun lẹwọn
lori iṣẹlẹ to
waye ninu oṣu keje, nibi ti wọn ti
pa alaga ijọba ibilẹ PDP ni Apapa iyẹn Ọgbẹni Adeniyi Abọriṣade. Ọkunrin naa ko fi ọrọ sabẹ ahọn sọ nigba to sọ gbogbo ipa ti Bọde
George ti ko lati mu ifasẹyin
ba ẹgbẹ naa
lati ibẹrẹ pẹpẹ.
Gẹgẹ bi alaye alaga naa, o
ni Bọde atawọn eeyan ẹ gbimọ pọ lati sọ nnkan ti ko ṣẹlẹ nipa wahala to waye
ni Eti Ọsa naa lati fi ran oun
lẹwọn, ṣugbon oun dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa atawọn agbofinro pe wọn ṣisẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ, wọn si ri i daju pe
oun ko mọ nnkankan nipa wahala
naa.
O ṣalaye siwaju pe, “Latigba ta a ti ṣe ipade ẹgbẹ oṣelu wa ni Ọrẹgun nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ ti fe to ẹgbẹrun lọna ogoji lati ri i pe
ibi ta a ti ṣe gan-an ko le gba wa
mọ, koda bi a ba ni ka a
ṣe ni ọfiisi wa, ko le gba ero,
idi niyi ta a fi pinnu lati maa ṣe ipade naa kaakiri awọn ijọba ibilẹ wa lati fi maa bawọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ.
![]() |
Bode George |
“A ti ṣe iru ipade bayii ni Ẹpẹ, Ọjọo, Amuwo Ọdọfin, Oṣodi- Isọlọ atawọn ibo mi-in ti wọn fi jẹ ijọba
ibilẹ mẹtala ti ko si wahala kankan nibẹ, iru ẹ naa la lo
ṣe ni Eti-Ọsa lọjọ naa. Ka too bẹrẹ lọjọ yen ni alaga PDP ijọba ibilẹ ibẹ to jẹ eeyan ti Bọde George ti kọkọ da awọn aga ijokoo ru, ti mo ni ki wọn fi silẹ”
O tun sọ ninu ọrọ ẹ pe ṣe lo
n sare wọnu mọto
ko too di pe wọn bẹrẹ rogbodiyan, lẹyin-o-rẹyin loun gbọ pe wọn ti
pa Aboriṣade ṣugbon nigba to ni awọn ti
Bọde George maa hun irọ jọ, wọn sọ pe
oun mọ nipa bi wọn ṣe
pa ọkunrin naa.
Ọpẹlọpẹ awọn
ayaworan ti wọn wa nibẹ, bawọn ọlọpaa ṣe ni koun yọju pẹlu awọn ẹlẹrii oun, toun de Panti, ṣe ni wọn da
gbogbo wọn satimọle. sugbon oun dupẹ pe
awọn ọlọpaa atawọn agbofinro ri okodoro ọrọ.
Salvador ni gbogbo erongba Bọde Geroge ni pe gbogbo nnkan ti ẹgbẹ naa ba fẹ ṣe, wọn gbọdọ wa ṣe
nile ẹ, to fi mọ ipade awọn
oloye ẹgbẹ ṣugbọn tawọn ko
gba fun un, o nile oun gan-an ju ile ẹ to n pọn le
naa lọ.
![]() |
Aborisade ti won yinbon pa ree |
Bakan naa lo sọ pe aimọye
owo tara oun loun ti na si apo ẹgbẹ naa, nitori ki ilọsiwaju
le de ba ẹgbẹ naa,
ko wa yẹ ki Bọde George ti ko lẹnu
nibẹ ni wọọdu ẹ maa
da gbogbo eto awọn ru, o wa ke si awọn oloye ẹgbẹ niluu Abuja lati le ọkunrin naa kuro ninu ẹgbẹ nitori agba ọbayejẹ ati agbẹyinbẹbọ jẹ ni.
0 Comments