Bi elekun ti n sun un, bee lawon mi-in n sepe nla nla, o si
jo pe nise ni won n ba gbajumo olorin emi nni, Yinka Ayefele kaanu gidigidi.
Ileese FRESH FM, iyen radio to wa lagbegbe Challenge n’Ibadan
ni won so pe ijoba ipinle Oyo kolu loru oni mojumo. Katapila ti awon agbefoba
gbe wa lo fenu so ileese ohun, ki oloju si too se e, ibi tawon eeyan maa n pe wo bii
iran, ti won si maa n kan saara si okunrin olorin to ti wa lori keke tawon aro
maa n lo fun opo odun yii ku iyanju se bee baje patapata.
Bi ile ti mo lawon eeyan ti n sare lo wo ohun to sele nibe,
nitori bi iroyin ohun ti gba igboro Ibadan kan lawon kan n so pe iro ni ko je
je bee, sugbon nigba ti won debe, ekun ni elomi-in sun, tawon kan si n gbe
ijoba Abiola Ajimobi sepe gidigidi.
0 Comments