GBAJUMO

IBO 2019: EGBE APC TO N SATILEYIN FUN IPOLONGO BUHARI NILE YORUBA BERE ISE

Aare Muhammed Buhari

Bi kuku-keke eto idibo odun 2019 se n sunmo etile, egbe alatileyin bi Aare Buhari yoo se wole lodun to n bo, iyen National Committee of Buhari Support groups ti so pe kaakiri orile-ede yii lawon ti setan bayii lati sise fun Buhari/Osibanjo ki won le wole leekan si i.
Laipe yii ni eka egbe naa nipinle Eko pe ipade lati se ifilole ati afihan awon oloye egbe naa ni gbongan nla GABOVIS Ojodu, Berger l’Ekoo.
Asiwaju awon obinrin ninu egbe oselu APC ni ile Yoruba, Oloye Yetunde Babajide, eni ti se Aare ileese YEFADOT Group of companies lo gba awon eeyan ohun lalejo. Kaakiri ijoba ibile metadinlogota (57) to wa nipinle Eko ni won ti yan asoju wa, ohun ti awon omo egbe ohun si so lojo naa ni pe awon setan lati polongo Aare Muhammed Buhari kaakiri ipinle Eko, ati pe o ti di dandan ki okunrin omo Hausa naa ati igbakeji e, Ojogbon Yemi Osinbajo tun se e leekan si i.
Awon omo APC n seleri lati polongo
fun un gidigidi
Oloye Yetunde Babajide ninu oro e dupe lowo gbogbo omo egbe fun emi akin ti won ni, bee lo fi da won loju pe, gbogbo ona pata to ye ni ijoba Buhari yoo se lati mu ki itura ba awon omo Nigeria.
O ni, “A dupe anfaani nla ti Olorun fun wa lati fi sepolongo ibo fun Aare Muhammed Buhari lodun 2015, ni bayii, ise ohun yoo tun bere, a si nigbagbo pe ere la o je bo nibe. Gbogbo wa pata ni mo dupe fun, ohun kan ti mo fe ki kaluku wa mo ni pe anfaani nla ti si sile fun wa lati jere ijoba Buhari, eto eyawo ti wa, bee lawon eeyan to ba fe sise agbe naa tun letoo sawon eto eyawo kan ti ko ni i ni won lara rara. Oselu ti awa n se, ki i se lati maa pin gaari tabi iresi pelu owo ti ko to nnkankan. Iru owo bee ki i tun aye eeyan se, nise lo maa n bani laye je.
“Fun idi eyi, ohun ti awa n se ti a o si tun maa se fun gbogbo awon to ba darapo mo wa ni kiko won lona ti awon naa le fi da duro, bee la tun maa fun won ni anfaani eto eyawo, eyi ti yoo mu opo bo lowo ise ati osi. Ki i se ohun to dara ki eeyan maa toro owo kiri lowo oloselu. Ohun ti awa so fun Aare Buhari niyen wi pe ko ma fun wa lowo, sugbon ko seto iranwo ti gbogbo awon eeyan wa nile loko ati lese-kuku yoo le ri anfaani e je. Bi a ti se soro yii, bee ni Aare gbo, o gba, o si fowo si i. Iyen gan-an lo so ileese wa deni to ni banki kereje to le ya ni lowo. Ti e ba kan si wa, a setan lati ran yin lowo.”
O te siwaju pe, “Lati nnkan bi odun mokandinlogun seyin ni eronpileeni to je ti orile-ede yii ti fo gbeyin, sugbon ni bayii, Aare Muhammed Buhari ti da a pada, bee ni ijoba e ko gba gbere lori a n kowo ilu je, gbogbo eyi naa lo n ta won lara ti awon kan fi n si kiri. Se e ri awon to kuro ninu egbe oselu APC yen, epo inu alikamo ni won, o si di dandan ki won o yo sonu. Asiko igba ti won lo yii gan-an ni nnkan yoo tubo dara si i, nitori bi okuta idina gan an ni won je tele ninu egbe wa.
Lara awon omo egbe nibi ipade
Iyalode Ojodu wa fi kun un oro e pe, ona kan pataki ti oun atawon elegbe oun fe lo lati fi polongo ipadabo Buhari bere lati ipinle Eko ati kaakiri ni sise awon eto iro-ni-lagbara fawon eeyan, eyi ti yoo fun won lanfaani lati le da duro.
O ni, “Eni ti a ba ko bo se le pa eja, nje to ba mo on tan, titi aye ko ni yoo maa janfaani e lo? Ohun ti awa n se nibi niyen, a o maa ko awon eeyan jo lati ko won lorisirisi nnkan to le so won di alagbara, eyi ti won le maa ta, ati eyi ti won le maa lo nile fun anfaani ara won paapaa. Bee lawon okunrin naa tun lanfaani lati kekoo nipa ise agbe, ti a o tun seto eyawo fun won, ni eyi ti ko ni ga won lara. Ko yo obinirn naa sile, gbogbo eyi, a n se e ki ojo iwaju Nigeria le dara ni, bee la o tun maa lo anfaani ba a se kora wa ko yii lati fi kede fun gbogbo omo Nigeria wi pe, Aare Muhammed Buhari ni ko tun pada sibe, nitori eletii-gbaroye to setan lati tun aye mekunnu se ni.”    
 Ninu oro ti alaga ijoba ibile idagbasoke Igbogbo Bayeku, Onarebu Adegbenga Basanya so lojo naa lo ti ro awon araalu lati gba kaadi idibo, ki won si ri i pe egbe oselu APC ni won tun dibo won fun leekan si i.
Bakan naa, Onarebu Taiwo Somade ni tie so pe, ko si ani-ani kankan, Aare Muhammed Buhari ni yoo tun sejoba Nigeria leekan  si i, ati pe ona kan pataki ti Nigeria le fi te siwaju ninu ayipada rere to n ba orile-ede yii lowo niyen.
Lara awon oloye egbe ti won wa nibe lojo naa ni; Onarebu, Taiwo Somade; Japhet Oguniyi; Adeniji Jubril; Doyin Johnson; Adegbenga Basanya; Sherif Oladejo; Oyekanmi Abiola; Prince Ade Ajayi; Aremu Toyin; Waheed Odunuga atawon mi-in.



Post a Comment

0 Comments