Gbajumo oloselu yii to tun je Agbe to
laami-laka tun so pe, “Egberun lona aadota naira la n ta eran tiwa, ohun ti a
si fe fi da awon eeyan loju ni pe, eran ti won ba ra nileese YEFADOT ni egberun
lona aadota naira (N50,000); ti won ba de agbo awon Hausa yoo ju bee lo daadaa.
Gege bi e se mo ileese wa, irorun araaalu lo je awa logun, bee la o nii ta
itakuta fun won.


“Eran to maa wo ileya lawa n ta. Bee lanfaani
si sile fawon eeyan lati wa ko o lopo yanturu lodo wa. A sese tun ko awon mi-in
de ni, a ti toju won daadaa, a ti won we won, bee la ti fun won lounje gidi, ko
si seni ti yoo ri won ti ko ni mo pe lododo ni won je oju ni gbese.”
O fi kun oro e pe, “Bi won ba se n ra agbo eyo
kan ni egberun lona aadota naira (N50,000) bee ni won yoo lanfaani si ororo
lita kan ati iresi ofada, bakan naa ni eto ti wa nile lati ba won gbe e dele. Fun
gbogbo eni to ba fe ra eyo-eyo tabi lopo yanturu, won le pe sori ero ibanisoro
yii 08035384150.”
1 Comments
Nice concept, may almighty Allah promote your efforts
ReplyDelete